Wasiu Ayinde kéde pé òun kò du ipò Awujalẹ mọ́ lẹ́yìn tó lulẹ̀ lórí ẹjọ tó pé tako ìgbésẹ̀ yíyan Awujale tuntun

Wasiu Ayinde wọ aṣọ aran aláwọ̀ pọpu àti fìlà rẹ

Oríṣun àwòrán, King Wasiu Ayinde Marshal /Instagram

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 4

Ọba orin Fuji, Wasiu Ayinde Marshal, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Kwam I, tí kéde pé òun ti yọwọ yọ ẹsẹ kúrò nínú ìgbésẹ̀ láti du ipò Awujalẹ tilu Ijebu Ode.

Kwam1 kéde bẹẹ nínú ìwé kan tó kọ ransẹ si ile ẹjọ́ nínú èyí tó ti sísọ lójú rẹ pé òun kò du ipò Awujalẹ náà mọ.

Agbẹjọ́rò Wasiu Ayinde lo gbé ìwé náà kalẹ síwájú ilé ẹjọ́ gíga tí ìpínlẹ̀ Ogun ni ọjọ́ Aje, ọjọ́ Kejilelọgbọn, oṣù Kejìlá ọdún 2025.

Igbesẹ Kwam I yìí si lo tẹle bí Iléẹjọ́ náà ṣe da ẹjọ́ tó pé ṣáájú nù láti dá ìgbésẹ̀ yíyan Awujale tuntun dúró.

Àwòrán ìwé ìpéjọ tí Wasiu Ayinde ṣe àti àwòrán òun gan fúnra rẹ

Oríṣun àwòrán, Collage

Ana ọjọ́ Aje yìí kan náà nile ẹjọ giga nipinlẹ Ogun náà ti wọgile ẹjọ ti Kwam1 pe lati bẹgi dina igbesẹ gomina Dapo Abiodun atawọn marun un mii lati yan Awujale tuntun.

Ṣaaju ni Kwam 1, ti agbẹjọro rẹ, Wahab Shittu (SAN) ṣoju fun ti rọ ile ẹjọ naa ko da igbesẹ yiyan Awujale tuntun duro titi ti ile ẹjọ yoo fi gbọ ẹjọ ti oun pe tako igbeṣe naa.

Amọ nigba ti ọrọ naa de iwaju adajọ A. A. Omoniyi, niṣe lo da ẹbẹ naa nu latari pe ẹbẹ ọhun ko lẹsẹ nilẹ ati pe ko si ẹri to dantọ lati gbe ẹbẹ naa lẹyin.

Kwam1 wọ aṣọ alawọ aro pẹlu fila funfun

Oríṣun àwòrán, k1deultimatedigitalmedia

Lẹyin ikede rẹ láti jọba lawọn eeyan kan ni Kwam1 kii ṣe ọmọ idile awọn, ati pe wọn ko mọ ọ ri

Adajọ ọhun tun paṣẹ pe ki wọn tete bẹri si n gbọ ẹjọ ti Kwam1 pe, o si kede ọjọ kẹrinla, oṣu Kinni, ọdun 2026 fun ibẹrẹ igbẹjọ ọhun.

Skip podcast promotion and continue reading
Èyí ni ìkànnì Whatsapp wa

Àjáàbalẹ̀ ìròyìn BBC News Yorùbá lórí WhatsApp rẹ

Darapọ̀ mọ́ wa nibì

End of podcast promotion

Ṣaaju ni Wasiu ti kọkọ kede pe oun nifẹ si ati jẹ oye Awujale gẹgẹ bii ọmọ oye ile Jadiara, to wa labẹ idile Fusengbuwa.

Lẹyin ikede rẹ lawọn eeyan kan bẹrẹ si n jade lati inu idile naa pe kii ṣe ọmọ idile awọn, ati pe wọn ko mọ ọ ri.

Kwam1 ri ọrọ ọhun bii irẹjẹ lo ṣe ko gba ile ẹjọ lọ lati lọ ja fun ẹtọ rẹ labẹ ofin.

Awọn ti Kwam1 pe lẹjọ ni idile Fusengbuwa, gomina Dapo Abiodun, alaga ijọba ibile Ijebu-Ode, atawọn mẹta mii.

Awọn to ku ni kọmiṣọna fun ọrọ ijọba ibilẹ ati oye jijẹ, Ganiyu Hamzat; akọwe ijọba ibilẹ Ijebu-Ode, Oke Adebanjo; ati alaga to n ri si ọrọ oye Awujale, Olorogun Sunny Kuku.

Kwam1 rọ ile ẹjọ pe kọ fofin de gbogbo awọn ti orukọ wọn jẹyọ ninu ipẹjọ naa pe wọn ko gbọdọ ṣe ohunkohun to rọ mọ oye Awujale jijẹ tabi yiyan ọmọ oye lasiko yii.

O bẹ ile ẹjọ ọhun pe eyikeyi ninu wọn tabi awọn aṣoju wọn ko gbọdọ bẹrẹ igbesẹ yiyan ọmọ oye titi ti ile ẹjọ yoo fi gbọ ẹjọ ti oun pe.

Ni bayii ti ile ẹjọ ti da ẹbẹ Kwam1 nu, ireti to ku fun bayii ni ohun ti yoo ṣẹlẹ lẹyin ẹjọ to pe, eyii ti ile ẹjọ yoo bẹrẹ si n gbọ lati ọjọ kẹrinla, oṣu Kinni, ọdun 2026.