Ayédèrú òṣìṣẹ́ aṣọ́bodè lu Soun Ogbomoso ní jìbìtì N39.5m, ọ̀rọ̀ di tilé ẹjọ́

Oríṣun àwòrán, Oba Ghandi Olaoye/ Facebook
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Oyo ti gbe ọkunrin kan, Ali Muhammed, ẹni ti wọn ni ayederu aṣọbode (custom officer) ni, lọ sile ẹjọ majisreeti ilu Ogbomoso, lori ẹsun pe o lu Soun Ogbomoso, Oba Gandi Olaoye, ni jibiti owo ti iye rẹ jẹ N39.5million.
Gẹgẹ bi iwe ipejọ ti wọn ka ni kootu naa nipa Muhammed, ẹni ọdun marundinlaadọta (45) ṣe wi, o pe ara rẹ ni ọga aṣọbode ipinlẹ Ọyọ (NCS Comptroller) fun Kabiyesi Olaoye Ghandi.
Olujẹjọ naa tun ṣeleri pe oun yoo ba ọba ra ọkọ ayọkẹlẹ lati ileeṣẹ aṣọbode, lasiko ti wọn ba n polongo ọja (auction) nita gbangba.
Ṣugbọn ileri ofo to pada ja si jibiti ni.
Eyi ni kootu ka si ẹsun pipe ara ẹni ni oun ti a ko jẹ, to lodi labẹ ofin 484 ofin iwa ọdaran ipinlẹ Oyo ti ọdun 2000, yatọ si ẹsun oni koko mẹta mi-in ti wọn tun fi kan an.
Bawo ni ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣe wáyé àti bí ìgbẹ́jọ́ ṣe lọ ní kóòtù?
Gẹgẹ bi wọn ti ka a ni kootu, Ali Muhammed ati awọn yoku rẹ ti ọwọ ofin ko ti i ba, huwa jibiti nipa gbigba N39,500,000 lọwọ Soun Ogbomoso, Oba Ghandi Olaoye.
Wọn ni eyi waye laaarin ọjọ kejila ati ikọkandinlogun oṣu Kẹwaa ọdun 2025.
Oja-Igbo, niluu Ogbomoso ni wọn si ti gbimọ pọ gba owo pẹlu ẹtan, ole jija ati pipe ara ẹni ni ohun ti a ko jẹ.
Yatọ si mọto ti Ali atawọn yoku rẹ ni awọn yoo ba Soun ra, ile ẹjọ sọ pe wọn tun gba owo irẹsi apo pupọ lọwọ oriade naa.
Eyi ni wọn ni o lodi labẹ ofin iwa ọdaran ipinlẹ Oyo, abala 419 ti wọn ṣe ni 2000.
Ile ẹjọ tun fi ẹsun gbigba N9,500,000 lọwọ Soun kan Ali ati awọn eeyan rẹ, wọn ni wọn lo owo naa fun anfaani ara wọn, lodi si ohun ti wọn tori rẹ gba a.
Nigba to n dahun ibeere kootu, pe ṣe o jẹbi tabi bẹẹ kọ, Ali Muhammed sọ pe oun ko jẹbi.
Eyi ni kootu ṣe fi aaye beeli silẹ fun un pẹlu miliọnu marun-un naira ati oniduro meji to n gbe lagbegbe kootu.
Igbẹjọ mi-in di ọjọ kejindinlọgbọn, oṣu Kin-in-ni ọdun 2026.














