Táńkà epo gbiná lọ́jọ́ Kérésì, èèyàn méji kú ní márosẹ̀ Eko sí Badagry

Aworan tanka to gbina to si n ṣe eefin

Oríṣun àwòrán, Others

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ni owurọ kutu Ọjọbọ, ọjọ kẹẹẹdọgbọn oṣu Kejila ọdun 2025 ti i ṣe ayajọ Keresimesi, ni eeyan meji di oloogbe, nigba ti tanka epo kan gbina loju ọna marose Eko si Badagry.

'Lagos State Traffic Management Authority' (LASTMA) to n ri si igbokegbodo ọkọ niluu Eko, fidi ijamba naa mulẹ.

Gẹgẹ bi Adari ikede LASTMA, Adebayo Taofiq, ṣe kede, ijamba naa waye lagbegbe Oto-Ijanikin, eyi ti ko jinna si ile ẹkọ Lagos State University of Education.

"Tanka agbepo kọlu ọkọ miran o si gbina, o pa awakọ kan ati obinrin ti wọn jọ wa ninu ọkọ naa."

Adebayo ṣalaye pe tanka kan to gbe epo disu n gbiyanju lati ya ọkọ kan silẹ ni, eyi to bu u lọwọ, to si padanu akoso ọkọ.

Lẹyin eyi ni tanka ọhun rọlu ọkọ miran, to si gbina bi adari ikede LASTMA ṣe ṣalaye ninu atẹjade to fi si oju opo X rẹ.

" Iwadii fi han pe ere asapajude lo fa ijamba yii. Awakọ tanka naa padanu akoso ọkọ rẹ nigba to n gbiyanju lati ya awakọ miran silẹ.

"Tanka naa kọlu ọkọ miran o si gbina, o pa awakọ kan ati obinrin ti wọn jọ wa ninu ọkọ naa."

O fi kun un pe awọn oṣiṣe LASTMA to wa nitosi sare ṣiṣẹ wọn bii iṣẹ, wọn da lilọ bibọ ọkọ duro lagbegbe naa ki ijamba miran ma baa ṣẹlẹ.

LASTMA rọ àwọn awakọ̀ láti máa tẹle òfin irinna lójú popo

Bakan naa lo ni wọn dena awọn eeyan to fẹran lati maa gbọn epo nibi ti tanka ba ti ṣubu, eyi to le fa iku pupọ si i.

Ọga agba LASTMA, Olalekan Bakare-Oki, fi aidunnu rẹ han si ijamba naa, o ni ijamba to ṣee dena ni.

Oki rọ awọn awakọ tanka lati maa ṣe suuru, ki wọn si maa tẹle ofin irinna lojuu popo.