Diego Maradona: Àgbàọ̀jẹ̀ agbábọ́ọ̀lù Argentina ṣiṣẹ́ abẹ lórí ẹ̀jẹ̀ tó dì sí i lọ́pọlọ lẹ́yìn ọjọ́ ìbí ọgọ́ta ọdún

Diego Maradona

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Agbaọjẹ agbabọọlu orilẹede Argentina nigba kan ri, Diego Maradona ti ṣiṣẹ abẹ lori ọpọlọ rẹ, iṣẹ abẹ naa si kẹsẹ jari.

Dokita gbajugbaja agbabọọlu naa, Leopoldo Luque lo ṣi aṣọ loju eegun ọrọ yii fawọn akọroyin.

Lọjọ Aje ni wọn gbe Maradona lọ si ile iwosan Ipensa to wa niluu Buenos Aires.

Dokita Luque sọ pe Maradona si wa labẹ ayẹwo bi ara rẹ ti n ya bọ diẹdiẹ lẹyin to ṣiṣẹ abẹ tan.

lati ile iwosan Ipensa ni wọn ti gbe Maradona lọ si ile iwosan Olivos Clinic to wa ni La Plata nibi to ti ṣiṣẹ abẹ naa.

Wakati kan ati ogun iṣẹju ni wọn fi ṣiṣẹ abẹ ọhun fun Maradona.

Diego Maradona ree to wọ ibomu

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Maradona, ẹni ọgọta ọdun ni akọnimọọgba ẹgbẹ agbabọọlu Gimnasia y Esgrima to n dije ninu liigi orilẹede Argentina.

Koda Maradona wa nibi ifẹsẹwọnsẹ Gimnasia y Esgrima pẹlu Patronato to waye lọjọ Ẹti tii ṣe ọjọ ibi ọgọta ọdun rẹ.

Ọpọ awọn ololufẹ ẹgbẹ agbabọọlu Gimnasia y Esgrima lo wa nita ile iwosan ti wọn ti ṣiṣẹ abẹ fun Maradona lati fihan pe gbọin-gbọin lawọn wa lẹyin rẹ.

Ọpọ ninu lo bẹrẹ si ni fi orukọ rẹ kọrin, kete ti wọn gbọ pe iṣẹ abẹ naa ti pari.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ẹgbẹ agbabọọlu Napoli ti Maradona ran lọwọ lati gba liigi Serie A lẹẹmeji naa ranṣẹ si i loju opo Twitter wọn.