Ondo Accident: Kíní ọ̀nà àbáyọ sí ìjàmbá ọkọ̀ tó ń wáyé lemọ́lemọ́ ní Ọjà Akungba,ní Ondo?

Oríṣun àwòrán, Road safety
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo ti ni awọn ti fi ami si ọja Akungba pe ki ẹnikẹni ma lọ sibẹ lasiko yii.
Eyi ko ṣẹyin ijamba ọkọ to waye agbegbe Ibaka ni Akungba Akoko, nipinlẹ Ondo, to si pa eniyan mẹrindinlogun.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro lo sọ bẹẹ fun BBC lori ibeere pe kini ijọba le ṣe lati ri wi pe opin de ba ijamba ọkọ to n fi ẹmi awọn eniyan ṣofo ni awọn ọja to wa ni opopona.
Tee-Leo Ikoro ni kii ṣe iṣẹ awọn lati ko ọja kuro ni oju popo, amọ o ni o dara kii ijọba ko awọn ọja kuro ni oju popo ki adinku ba ijamba ọkọ ojojumọ.
''A ti fi ami si oju popo ki ẹnikẹni ma gba ibẹ kọja ni asiko yii nitori iwadii ṣi n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa.''
''Ami naa yoo wa nibẹ titi iwadii lori iṣẹlẹ naa yoo fi pari''
Bakan naa ni Ajọ to n risi irina loju popo ti kesi awọn ijọba ibilẹ lati gbe igbesẹ lati ko awọn ọja kuro loju popo.
Ajọ FRSC sọ ọrọ yii nitori iṣẹlẹ to to ṣẹlẹ ni ọja naa kọ awọn lominu.
- Ta ni Wolii Olapade Agoro tó re ibi àgbà ń rè tí ayé ń pariwo rẹ̀ yìí?
- Ìbẹ̀rù-bojo gbalẹ̀ ní Oyigbo lẹ́yìn tí ọlọ́páà mẹ́ta àti sọ́jà kú nínú rògbòdìyàn EndSARS
- Banki Nàìjíríà, CBN ṣàlàyé nípa àwọn tó máa rí gbà nínú owó ìrànwọ́ N75b tíjọba gbé kalẹ̀
- Ta ni Wolii Olapade Agoro tó re ibi àgbà ń rè tí ayé ń pariwo rẹ̀ yìí?
''Ko dara ki awọn eniyan ma a na ọja loju popo nitori ijamba ọkọ''
''Ti ijamba ọkọ ba ṣẹlẹ ni oju popo, o ma n mu ọpọ ẹmi lọ nitori awọn eniyan ma n su jọ si oju popo lati ta ọja wọn''.
Ajọ EFSC sọ wi pe awọn meje ni awọn doola ẹmi wọn ninu ijamba ọkọ naa, amọ ti ẹmi mẹrindinlogun ba iṣẹlẹ naa lọ.
Nibayii, gbogbo igbiyanju wa lati ba ijọba ipinlẹ Ondo sọrọ lori igbesẹ ti wọn n gbe lati ri wi pe iru iṣẹlẹ naa ko waye mọ lo jasi pabo.
Ọ̀pọ̀ ẹ̀mí ló ṣòfò nibi ìjàmba tó wáye ni Akungba nìpińlẹ̀ Ondo
Ọ̀pọ̀ ènìyàn ló ti ba ìjàmbá alẹ́ ọjọ́ Abámẹ́ta rin ní ìlú Akungba Akoko, ìjọba ìbílẹ̀ Iwọ oorun-Gúúsú nípìnlẹ̀ Ondo.

Oríṣun àwòrán, Road safety
Ìròyìn ni ijàmba ọkọ̀ náà kan àjàgbé akẹ́ru to yawọ inú ọjá to si pa ọ̀pọ̀.
Gẹ́gẹ́ bi àwọn ti ọ̀rọ̀ náà sojú wọn ṣe sọ, ìjànú ọkọ̀ àjàgbé tó kó ìrẹsì ló já èyi si lo mú ki ọkọ̀ náà yawọ si inú ọjà tí o sì pà ọ̀pọ̀ ènìyàn.
Awọ́n ti wọn ni iṣẹlẹ naa ṣoju wọn ní ǹkan bi aago méje àbọ̀ alẹ́ ló ṣẹlẹ̀, àti pé 'gbàrà ti ìṣẹ̀lẹ̀ náà ṣẹ, okú ènìyàn mẹ́wàá ni àwọn fàyọ, sùgbọ́n yóò tó ènìyàn ogún tó ba iṣẹ̀lẹ̀ náà rìn.
Sùgbọ́n agbẹnusọ ilé iṣẹ́ ọlọ́pàá ìpińlẹ̀ Ondo Tee-Leo Ikoro sàlàyé pé, ènìyàn mẹ́jọ ni awọn le fi ìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó kú nínú ìṣẹ̀lẹ̀ náà.

Oríṣun àwòrán, Road safety
Ó ní, " Bí a ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí ènìyàn mẹ́jọ ló ti bá ìṣẹ̀lẹ̀ náà lọ, bó tilẹ̀ jẹ́ ó ṣeéṣe ki àtún ri àwọn míràn nítórí àwọn kan ti hà sí abẹ́ àjàgbé náà"
Ènìyàn méjì pàdánù ẹ̀mí wọn nínú ìjàmbá ọkọ̀ tó wáyé ní Abúlé Ẹ̀gbá, ní ìpínlẹ̀ Eko

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Ijamba ọkọ laarin ọkọ mẹta ti mu ẹmi eniyan meji lọ ni ipinlẹ Eko.
Ijamba ọkọ naa waye ni opopona Al Maruf, Abule Egba ni ipinlẹ Eko.

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Ninu atẹjade ti ileeṣẹ to n risi iṣẹlẹ pajawiri nipinlẹ Eko, LASEMA fi lede ni wọn ti sọ wi pe ọkọ to n gbe oti lọ lo yidanu sọri ọkọ meji, ti ohun to wa ninu rẹ si danu.
LASEMA ni ibanujẹ ọkan lo jẹ fun awọn wi pe ẹmi meji lọ si iṣẹlẹ naa, ti awọn si ti ko oku wọn lọ si ile igbokusi ni ilu Eko.
Bakan naa ni wọn fikun pe awọn ti ko awọn ọkọ meji yoku kuro loju ọna, ki sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ le dinku.

Oríṣun àwòrán, LASEMA
Ajọ LASEMA naa wa rọ awọn awakọ lati maṣe sare asapajude loju popo.














