EndSars Protest Update: Àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n ń bẹ jàńdùkú àmọ́ wọ̀n kò gbọ́

Oríṣun àwòrán, Adetomi Akin
Ileesẹ to n se akoso ọgba ẹwọn nilẹ wa, ẹka tipinlẹ Ondo ti salaye bi awọn janduku se ja ọgba ẹwọn Okitipupa laarọ Ọjọbọ.
Osisẹ alarena fun ileesẹ to n sakoso ọgba ẹwọn ni Ondo, Ogundare Babatunde, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ salaye pe aago mẹwa abọ aarọ lawọn janduku naa de si ayika ọgba ẹwọn naa.
Ogundare ni awọn janduku naa pọ biba, ti wọn si to ẹgbẹrun meje, eyi to mu ki apa awọn osisẹ ọgba ẹwọn naa ma ka wọn.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Buhari kọ́ ni ìṣòro wa, bó ṣe wà láti láéláé rèé - Fr Mbaka
- Àwọn ọ̀dọ́ fi ọ̀nà àrífín pe Tinubu lórí aago àmọ́ ó ní òun kò mọwọ́-mẹsẹ̀ nípa ìpànìyàn Lekki
- Wo díẹ̀ lára dúkìá tí jàǹdùkú sun níná l‘Eko torí ìwọ́de EndSARS
- Á ràgà bo CCTV Lekki bí i ẹ̀rí tó dájú fún ìwádìí ìpànìyàn - Sanwo-Olu
- SERAP gbé ìjọba àpapọ̀ lọ ilé ẹjọ́ àgbáyé ICC lọrí ẹ̀sùn ìpànìyàn
- "Jàǹdùkú gún ẹ̀gbọ́n mi lọ́rùn, jó ilé àti mọ́tò wa méjì, kòròfò la wà"
- Olùwọ́de 12 kú ni Lekki, 38 lapapọ kú lọ́jọ́ Isẹ́gun, 56 ni àròpọ̀ àwọn tó bá ìwọ́de lọ - Amnesty International
- Osinbajo gbarata lórí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki, ó ní ìdájọ́ òdodo yóò wà
"A ba wọn sọrọ, a bẹ wọn ki wọn ja ọgba ẹwọn naa, awọn ẹyin eti wọn ni gbogbo ẹbẹ wa n bọ si."
Ọgba ẹwọn naa ni ẹlẹwọn mejidinlọgọwa, to si kere jọjọ.

Oríṣun àwòrán, Adetomi Akin
Ogundare fikun pe ẹlẹwọn mejidinlaadọta lo wa ni ọgba ẹwọn naa, gbogbo wọn si ni awọn janduku shun tu silẹ.
"Lara awọn ẹlẹwọn naa tiẹ taku pe awọn ko lọ, wọn ni kawọn janduku naa fi awọn silẹ ninu ọgba ẹwọn yii amọ se ni awọn janduku ọhun fi tipa le wọn jade."
Alarina ileesẹ ọgba ẹwọn l'Ondo ni awọn janduku naa wa pẹlu ibọn, ada atawọn ohun ija oloro lati kọlu ọgba ẹwọn naa.
O ni "Wọn dana sun awọn mọto wa, wọn tun se awọn osisẹ kan lese sugbọn ko si ẹni to ku sinu isẹlẹ yii."

Oríṣun àwòrán, Adetomi Akin
Ẹlẹ̀wọ̀n 1,993 la ri ẹ̀rí pé wọ́n sá lọ́gbà ẹ̀wọ̀n méjì ní Ìpínlẹ̀ Edo- Ìjọba Nàìjíríà

Oríṣun àwòrán, @kizento_
Oludari eto iroyin nileeṣẹ to n ri si ọrọ abẹle ni Naijiria, Mohammed Manga lo fi ọrọ yi to awọn akoroyin leti.
O ni bayi, ẹlẹwọn ẹgbẹrun meji din meje lawọn ri ka pe wọn ríbi salọ kuro lẹwọn mejeeji to wa ni ipinlẹ Edo.
Ìjọba ní yato sí pe wọn tu awọn ẹlẹwọn silẹ, awọn to kọlu ogba ẹwọn wọnyi tun ji nkan nibẹ to fi mọ ibon nibi ti wọn kọ wọn si.
Manga ni "wọn rọ ara wọn wa ni pẹlu nkan ija ti wọn si kọlu awọn ẹṣọ to wa lẹnu iṣẹ"
Ṣugbọn o salaye pe gbogbo nkan ti pada sipo t'awọn si ti fikun agbara awọn to n pese aabo lawọn ọgba ẹwọn jakejado Naijiria.
Mango fikun ọrọ rẹ pe iwadii ti bẹrẹ lati mọ ẹkunrẹrẹ ipa ti ikọlu naa ni.
O ni " iwọde pẹlẹ kutu ko tako ofin to sì tun jẹ ẹtọ awọn ara ilu ti ofin fún wọn.
Amọ, iwa ọdaran to tako eredi ohun ti wọn n ja fun ni ki eeyan ṣe ikọlu si ọgba ewon"
O pari ọrọ rẹ pe "aaye aabo to gbọngbọn ni ọgba ẹwọn jẹ.Aaye taa sì n ko awọn ti ilẹ ẹjọ ti dajọ ẹwọn fun ni aaye yi jẹ"
- Buhari, máṣe gbá ìpànìyàn Lekki sórí ààtàn, kò yẹ́ kí ológun yin ọ̀dọ́ níbọn - Bode George
- 2015 ni mo ti ń kígbe pé gudugbẹ̀ máa já ní Nàíjíríà - Oyedepo
- Àwọn oníjàgídíjàgan kọlu aàfin Oba ìlú Eko àti iléesẹ́ ìròyìn LTV
- Mọ̀ nípa DJ Switch, akíkanjú obìrin tó sàfihàn fídíò ìpànìyàn Lekki bó ṣe ń wáyé
- Ooni Ogunwusi àti Wole Soyinka kòrò ojú sí ìṣẹ̀lẹ̀ Lekki Tollgate

Oríṣun àwòrán, Getty Images
"Ẹ ràn wá lọ́wọ́ láti rí àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó sálọ ní Oko àti Benin padà"
Ileesẹ to n sakoso ọgba ẹwọn ni oun ti n gbe igbesẹ lati da nnkan pada sipo lawọn ọgba ẹwọn mejeeji.
EndSars Protest in Edo: Iléeṣẹ́ alákòsóo ọ̀gbà ẹ̀wọ̀n bẹ aráàlú láti báwọn wá ẹlẹ́wọ̀n tó sálọ
Ileesẹ to n ṣakoso awọn ẹlẹwọn ni Naijiria ti kesi ara ilu lati ran awọn lọwọ, nipa mimu awọn ẹlẹwọn to sa lọgba ẹwọn ilu Benin lọjọ Aje pada wa.
Atẹjade kan lati ọdọ alukoro ileesẹ naa, AC Njoku lo fidi ọrọ yii mu'lẹ.
Njoku salaye pe, awọn oluwọde labẹ asia ENDSARS kan lo ṣe ikọlu si ọgba ẹwọn to wa nilu Benin-City ati Oko, ti wọn si tu awọn ẹlẹwọn ti ileẹjọ ni ki wọn wa latimọle silẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìwọ́de EndSARS ló ń sọ pé inú ń bí àwọn ọ̀dọ́, ìjọba, ẹ náání wọn - Obasanjo
- Ẹni iyì àti akíkanjú tó ṣe gbẹ́kẹ̀lé làwọn èèyàn Akure, ilú ìyá mi - Seyi Makinde
- Ẹ̀yin ọ̀dọ́ ti rí èrè ìwọ̀de yín lórí EndSARS àmọ́ ẹ ṣọ́ra, kẹ má baà sọ èrè náá nù - Tinubu
- Owó ìrànwọ́ Covid-19 dé, ìjọba fẹ́ san ₦75bn fún 54,000 olókoòwò
- Ìjọba ìpínlẹ̀ Eko ti iléèwé pa nítorí ìwọ́de #EndSARS
- Ìrẹ̀wẹ̀sì ń bá wa torí ìdánwò NECO tẹ ń ṣún síwájú lọ́pọ̀ ìgbà - Akẹ́kọ̀ọ́, ọ̀gá iléèwé
- Agbára ìgbìmọ̀ ìdájọ tí mo gbé kàlẹ̀ yóò dé ọ̀dọ̀ àwón ólọ́pàá tó ti kúrò lẹ́nu iṣẹ́ tẹ́lẹ̀- Sanwo Olu
- Wo àwọn orílẹ̀èdè míràn tó ń fojú winá ìwọ́de bíi ti ENDSARS
O ni awọn ko ti le sọ pato iye awọn to sa níbẹ ati pe awọn yoo fi to ara ilu leti ni kete tàwọn ba pari iwadii.
O ni awọn n gbe igbesẹ lati da nkan pada sipo lawọn ọgba ẹwọn mejeeji yii.
Labẹ eyi, o ni ikọ ileesẹ naa to n gbe ibọn n ṣiṣẹ takuntakun lati wa ojutu si ọrọ ọhun.
O wa rọ ara ilu lati maa ba iṣẹ wọn lọ laisi idiwọ, ki wọn ṣi maṣe jẹ ki ẹnikẹni lo wọn lati da alaafia ipinlẹ naa ru, nipa biba ohun ini ijọba ati araalu jẹ.

Oríṣun àwòrán, Nigeria prison Sevice
Bi a ko ba gbagbe awọn ẹlẹwọn kan sa lọgba ẹwọn nigba ti awọn eeyan kan ti wọn fura si pe wọn lawọn n se iwọde ENDSARS, yabo ọgba ẹwọn ilu Benin-City ati Oko.
Ẹlẹ́wọ̀n 200 sálọ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n Benin lásìkò ìwọ́de EndSars

Oríṣun àwòrán, https://twitter.com/Postsubman
O kere tan ẹlẹwọn to le ni igba lo salọ kuro ni ọgba ẹwọn to wa ni ilu Benin, nipinlẹ Eko lasiko ifẹhọnuhan EndSars.
Awọn ti iṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ fun BBC pe awọn janduku to ja iwọde naa gba, ti gbogbo ọna to jade si ọgba ẹwọn naa, ti wọn ko si jẹ ki ẹnikẹni kọja abi wọle si agbegbe ọgba ẹwọn naa.
Wọn ja ilẹkun to wa ni oju ọna wọle, wọn si bori awọn ẹsọ alaabo to wa lẹnu iṣẹ lasiko naa, ki wọn to tu awọn ẹlẹwọn silẹ.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ìjọba da ológun sí Abuja láti dẹ́kun ìwọ́de
- Mo fura pé ẹ fẹ́ da Nàíjíríà rú, ń kò ṣe ìwọ́de mọ́ - Segalink, agbátẹrù ìwọ́de yọwọ́
- Ìwọ́de EndSARS gboró n‘Ibadan, kò sẹ́ni tó le wọlé tàbí jáde
- "Buhari, ìwọ́de yóò yíwọ́, tó gbá jẹ́ káwọn ológun bá bẹ̀rẹ̀ ‘Operation Crocodile Smile’ "
- Ìjọba Eko pàdánù ₦234m láàrín ọ̀sẹ̀ kan torí ìwọ́de End SARS
- Bí o bá fẹ́ darapọ̀ mọ́ ikọ̀ ọlọ́pàá SWAT tí yóò rọ́pò SARS, wo àmúyẹ tí o gbọ́dọ̀ ní
- Aisha Buhari polongo àwo orin tó ní Nàíjíríà ń ṣun ẹ̀jẹ̀ lásìkò ìwọ́de
Iṣẹlẹ yii waye laarin iwọde ifẹhọnuhan tako ifiyajẹni awọn ọlọpaa kaakiri orilẹede Naijiria.
Ilẹeṣẹ ọlọpaa ni ipinlẹ Edo sọ fun BBC pe, awọn janduku naa tun ṣe ikọlu si agọ ọlọpaa kaakiri ipinlẹ naa, ti wọn si n ko gbogbo ohun ija wọn lọ.

Oríṣun àwòrán, @kizento_
Koda, wọn tun tu awọn afurasi to wa ni ahamọ silẹ, ti wọn si tun jo lara agọ ọlọpaa kan.
Nibayii, ijọba ipinlẹ Edo ti paṣẹ ofin konile-o gbele ọlọjọyipo kaakiri ipinlẹ naa.
Irọ́ ni ò, kìí ṣe àwọn afẹ̀họ́núhàn EndSars ló tú àwọn ẹlẹ́wọ̀n sílẹ̀ ní Benin- Oby Ezekwezili
Ọpọlọpọ awọn ọmọ Naijiria lo ti bẹrẹ si ni fi ero wọn han lori bi awọn ẹlẹwọn ṣe tu jade kuro ni ọgba ẹwọn to wa ni ilu Benin.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 1
Loju ọpọ ikansiraẹni Twitter ni awọn eniyan ti n sọrọ tako iroyin pe awọn afẹhọnuhan EndSars lo tu awọn ẹlẹwọn naa silẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 2
Bakan naa ni gbajugbaja afẹsẹkubiojo, Anthony Joshua, pẹlu ajafẹtọ ọmọniyan, J. J Omojuwa ní kìí ṣe EndSars ló wà nídìí àwọn ẹlẹwọn tó sálọ ní ilu Benin.
Anthony Joshua lori Twitter ni nkan miran lo n ṣẹlẹ lorilẹede Naijiria, nitori pẹlẹ putu ni awọn afhọnuhan naa fi n ṣe iwọde wọn.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 3
Ninu ọrọ tirẹ, J.J Omojuwa ni o da ohun loju wi pe awọn ọdaran to tu ẹlẹwọn silẹ kii ṣẹ awọn afẹhọnuhan EndSars, nitori naa ifẹhọnuhan wọn ko si fun iwa ọdaran lawujọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 4

End of X post, 5
Obaseki kéde òfin kónílé-ó-gbélé ní Edo torí ète jíjá ọgbà ẹ̀wọ̀n
Ijọba ipinlẹ Edo ti kede ofin konile-o-gbele oni wakati merinlelogun, bẹrẹ lati irọlẹ oni lọ.
Gomina ipinlẹ naa, Godwin Obaseki lo kede bẹẹ loju opo Twitter rẹ lẹyin ti awọn janduku darapọ mọ awọn oluwọde End SARS ti wọn si gbiyanju lati tu awọn ẹlẹwọnm ka silẹ ni ahamọ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 6
Obaseki ni igbesẹ naa pọndandan nitori awọn janduku to n ba nkan jẹ lasiko ifẹhọnuhan to n waye ni ipinlẹ naa.
O bi biotilẹjẹpe awọn bọwọ fun ẹtọ awọn araalu lati ṣe ifẹhọnuhan, amọ awọn ko le e ma wo ki awọn onijanduku ma a ba dukia ati ohun ini awọn eniyan jẹ.
Gomina ipinlẹ Obaseki naa wọ awọn obi lati bojuto ọmọ wọn ki wọn si kilọ fun wọn lati duro silẹ lasiko ofin konile o-gbele ti wọn kede naa.
Obaseki ni ẹtọ ijọba ni lati bojuto ẹmi ati dukia awọn eniyan nipinlẹ Edo, nitori naa ẹnikẹni ti wọn ba gbamu to tapa si ofin isede naa yoo foju wina ijọba.
Ẹwẹ, abẹnugan ile aṣofin nipinlẹ Edo, Marcus Onobum ti ni lootọ ni awọn aworan to n ja ranyin lori ayelujara wi pe awọn ẹlẹwọn gbiyanju lati sakuro ni ọgba ẹwọn amọ wọn ko ṣe aṣeyọri.
Onobum ni biotilẹjẹpe oun ko ni ẹkunrẹrẹ iroyin nipa iṣẹlẹ naa, amọ awọn alaṣẹ ni ọgba ẹwọn naa ni awọn ti kapa awọn ẹlẹwọn naa.

O ni iwadii n lọ lọwọ lori iṣẹlẹ naa nitori awọn afẹhọnuhan naa ti ti gbogbo opopona to wọ ilu Benini ti wọn ko si jẹ ki awọn eniyan kọja.
Agbẹnusọ ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Edo, Chidi Nwabuzor ni oun ko le fi idi iṣẹlẹ naa mulẹ nitori gbogbo awọn ọlọpaa lo joko si ile wọn.
Nitori awọn afẹhọnuhan ko jẹ ki awọn ọkọ raye kọja kaakiri ipinlẹ naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 7
Àwọn janduku tú àwọn ẹlẹ́wọ̀n sílẹ̀ ní ìlú Benin lásìkò ìfẹ̀họ́núhàn EndSars
Amọ, iroyin to n tẹlẹ lọwọ sọ wi pe awọn janduku ti tu awọn ẹlẹwn silẹ ni ọgba ẹwọn ni ilu Benin.
Fidio to n ja ranyin lori ayelujara ṣe afihan awọn eniyan to n ho ye e nigba ti awọn ẹlẹwọn naa n fo jade gba ogiri ọgba ẹwọn naa.
Ọgba ẹwọn to wa ni agbegbe Reservation Road Junction ni Sapele Road, Benin City ni iṣẹlẹ naa ti waye.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 8
Fidio naa tun ṣe afihan bi awọn ẹlẹwọn ohun ṣe n rin loju titi lẹyin ti wọn tu wọn silẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post, 9
Awọn eniyan to n fesi si iṣẹlẹ naa n kesi awọn afẹhọnuhan EndSars lati dawọ duro lori ifẹhọnuhan naa nitori awọn janduku ti gba a mọ wọn lọwọ bayii.
Amọ awọn eniyan kan fẹsi wi pe awn afẹhọnuhan lo ṣe eyi, bikoṣe awọn janduku nitori awọn afẹhọnuhan ko le e lọ si ọgba ẹwọn lati lọ ṣọṣẹ.