Iyaloja Oyo state: Àwọn ọlọ́jà ń sèdárò Ìyálọ́jà ìpínlẹ̀ Oyo, Wuraola aya Kola Daisi tó dolóògbé, wọ́n yan asojú míràn

Ẹgbẹ awọn ọlọja nipinlẹ Ọyọ ti sapejuwe iyalọja ipinlẹ Oyo gẹgẹ bi akọni obinrin to jẹ oninu ire, lẹyin to papoda lẹni ọdun mẹrindinlọgọrun.
Alhaja Wuraola Asake Kola Daisi dagbere faye leni odun merindinlaadorun un.
Oloye Rotimi Jogunosinmi to je mogaji agboole Jogunosinmi ni adugbo Oja Oba to tun je omo oloogbe lo fidi e mule.
O ni eyin DRovans ni agbegbe Ringroad ni Ibadan ni iyaloja yoo ti wo kaa ile lo,.
Lodun 2008 ni komisonna fun oro obinrin ati idagbasoke agbegbe nigba naa, Arabinrin Deborah Oyelade fi Oloogbe Wuraola je iyaloja lasiko gomina Adebayo alao Akala.
Aarẹ ẹgbẹ awọn ọlọja naa ni ilu Ibadan, Alhaji Dauda Oladepo lo sọrọ naa lasiko to n ba awọn ẹgbẹ kẹdun ni ilu Ibadan.
Oladepo ni iku iyalọja naa ba wọn lọkan jẹ gidigidi, to si ba wọn lojiji.
Ẹwẹ, ẹgbẹ awọn ọlọja naa ti kede pe awọn ti yan Yeye Justina Iyabode Ogundoyin lati ṣe adele iyaloja ipinlẹ Ọyọ ni kiakia.
Ninu ọrọ rẹ, Iyalode Ogundoyin ṣe apejuwe Iyalajẹ to doloogbe naa gẹgẹ bi iya rere to duro ni ipo iya fun ọpọlọpọ eniyan.
Agogo mẹrin, ọjọ kejilelogun, oṣu kẹwaa naa ni wọn yoo sin ni ile rẹ.
Awọn ọlọja naa ni awọn ko le e gbagbe iyalọja naa titi ayeraye, nitori o duro ti wọn nigba to le ati igba to dara.
Bakan naa ni wọn gbadura fun awọn ẹbi naa lati mu ọkan le, wi pe edua yoo wa pẹlu wọn.
- Tani Oke Obi-Enadhuze: tí orúkọ rẹ̀ gba orí ayélujára kàn lẹ́yìn wàhálà #Lekki tollgate?
- Mo fura pé ẹ fẹ́ da Nàíjíríà rú, ń kò ṣe ìwọ́de mọ́ - Segalink, agbátẹrù ìwọ́de yọwọ́
- "Buhari, ìwọ́de yóò yíwọ́, tó ba jẹ́ ki ológun bẹ̀rẹ̀ ‘Operation Crocodile Smile’ "
- 2015 ni mo ti ń kígbe pé gudugbẹ̀ máa já ní Nàíjíríà - Oyedepo















