Police Recruitment: Ìlé ẹjọ́ ti pàsẹ pe ki ilé iṣẹ́ ọ̀lọ́pàá dá ìgbaniwolé dúró

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ilé ẹjọ́ gígá nílùú Abuja ti pàsẹ pe ki àjọ ọlọpàá dá ètò ìgbànisísẹ́ ẹgbẹ̀run mẹ́wàá ti wọ́n ń ṣe lọ́wọ́ dúró.
Adajọ Inyang Ekwo lofi idájọ náà jànlẹ pe ki wọ́n dááduro titi ti igbẹ́jọ́ tí ajọ ọlọpàá pe.
- Iléeṣẹ́ Instagram wọ́gilé App "Augmented Reality filters" lórí ẹ̀rọ rẹ̀
- Ìgbẹ́jọ́ Naira Marley sún síwájú bí àwọn agbẹjọ́rò ń jà sí àga ìjókòó
- Kí ló dé tí Ilé ẹjọ́ sún ìgbẹ́jọ́ Naira Marley sí ọ̀la?
- Gbogbo ilé ọmọ aláìgbọràn nílẹ̀ Yorùbá, Ọlọ́pàá ń bọ̀ wá yẹ̀ yín wò
- Nínú òkuǹkùn birimù birimù ni mo wà báyìí ni ilé Ìjọba - Igbakeji Gomina Kogi àná
- Ǹjẹ́ o mọ̀ pé ètò ìdìbò kan wà tí erin àti òkúta Dáyámọ́ǹdì leè yí èsì rẹ̀ padà
Eyi wáye lẹ́yin ti wọ́n so igbẹ́jó náà pọ̀ adájọ́ àgbà Abubakar Malami nínú ejọ náà.
Àwọn míràn ninu igbẹjọ náà ni Ọga agba ọlọpàá àti mínísita fun ọ̀rọ ọlọpàá.
Adajọ Ekwo ní gbogbo àwọn ti ọ̀rọ̀ náà kan ní a wọn gbọdọ tẹ̀lé ìdájọ náà titi yóò fi pari ọ̀rọ̀ naa.
Wàhálà ejọ́ yìí bẹ̀rẹ̀ lásìkò tí àjọ ọlọpàá fẹ̀sùn kan ilé iṣẹ́ ọlọpàá pé wọ́n já ètò igbànisísẹ́ náà gbà mọ àwọn lọ́wọ́.
Àjọ ọlọpàá fẹ̀sun kan ilé iṣẹ́ ọlọpàá pé wọ́n ti tọ́wọ́bọ ètò àwọn ìgbàniwọle náà nipa àyípada àwọn orúkọ ninu iwé orukọ.
Tí ẹ o ba gbàgbé ètò ìgbaniwọlé ọlọpàá náà bẹ̀rẹ̀ ní òpin ọdún to koja.













