Ajax vs Chelsea: VAR ṣ'ègbè lẹ́yìn Chelsea f'ogun ẹ̀yín ja Ajax mọ́lé

Oríṣun àwòrán, @Chelsea4Pidgin
Ifẹsẹwọnsẹ UEFA Champions League laarin ikọ Ajax ati Chelsea to waye lalẹ oni le koko bi oju ẹja, ṣugbọn ikọ Chelsea fẹ Ajax danu nile wọn.
Ni igba ti idije naa wọ iṣeju mẹtalelọgbọn ni Quincy Promes sọ ayo kan wọle fun ikọ Ajax, ṣugbọn lẹyin isẹju die si ti wọn wo oju ẹrọ ni VAR ni rẹfiri wọgi le goolu ọhun.
Ọ̀mì ni ikọ memeji gba ni ipari abala akọkọ ifẹsẹwọnsẹ ọhun.
- Abẹ̀ṣẹ́kùbíòjò Patrick Day dèrò ọ̀run lẹ́yìn tó gba ẹ̀ṣẹ́ s'órí!
- Israel Adesanya fi ẹ̀ṣẹ́ mú ẹ̀jẹ̀ jáde nímú Whittaker láti gba àmì ẹ̀yẹ UFC
- A kò mọ̀ bóyá a le è san owó osù tuntun fún òsìsẹ́ - Ìjọba Ondo, Oyo, Kwara jẹ́wọ́
- 'Àwọn ti Micra ló jẹ̀bi rògbòdìyàn awakọ̀ tó wáyé lánàá n'Ìbàdàn'
- Seun Egbegbe lo ọdún méjì àti oṣù méje lẹ́wọ̀n láì tìí san béèlì rẹ̀
Gbogbo akitiyan Quincy Promes ninu abala keji ifẹsẹwọnsẹ naa lati sọ bọọlu sinu awọn ikọ Chelsea lo ja si pabo, ko to di pe wọn parọ rẹ.
Ṣugbọn nigba ti o ku iṣeju mẹrin ki ifẹsẹwọnsẹ ọhun pari ni Michy Batshuayi fi ibinu sọ ami ayo kan sinu awọn ikọ Ajax.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Eyi mu ki akọnimọgba ikọ Ajax Erik ten Hag, parọ awọn ọmọ rẹ meji ni wara wara, ṣugbọn ẹpa ko boro mọ.
Bo tilẹ jẹ pe akọnimọgba ikọ Chelsea naa parọ lara awọn ikilọ rẹ, ti wọn gbiyanju lati sọ ayo miiran sinu awọn.
Lẹyin iṣẹju mẹrindinlọgọrun un ni ifẹsẹwọnsẹ naa pari ni ikọ Chelsea fẹ Ajax danu bi abẹbẹ pẹlu ami ayo kan si odo.












