Torture Centre: Buhari pàsẹ àbẹ̀wò sí gbogbo ilé ọmọ aláìgbọràn

ọlọpaa ati àwọn olutusilẹ
Àkọlé àwòrán, Kaduna Torture Centre: Ààrẹ Buhari pàsẹ kí ilé iṣẹ́ ọlọpàá gbọn ìpínlẹ̀ 36 yẹ́bẹ́yẹ́bẹ́

Ààrẹ Muhammadu Buhari ti pàsẹ kí ilé iṣẹ́ ọlọpàá ṣe ìwádìí gbogbo àwọn ilé ọmọ alàìgbọ̀nran to ba wà ní ìpínlẹ̀ mẹrẹẹrindilogoji, to fí mọ Abuja, tii se olúùlú orilẹ̀-èdè Naijiria.

Ààrẹ Buhari pa àsẹ yìí lẹ́yìn ti gómìnà ìpínlẹ̀ Kaduna, Mallam Nasir el-Rufai kọ́wọ̀rìn pẹ̀lú àwọn ọlọpàá nipinlẹ Kaduna, láti lọ tú ilé ti wọn ti n mú àwọn ọdọ́ nígbèkun fún ìbáwí, èyí ti wọ́n pe orúkọ rẹ̀ ní Mallam Niga Rehabilitation Centre, to wa ni ijọba ìbílẹ̀ Rigasa ní ìpínlẹ̀ Kaduna.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Ààrẹ ní ìjọba tó ń bẹ lóde kò fí ààyè gbà ìwá ìmúnilẹrun, àìbọwọ̀ fún ẹ̀tọ́ ọmọniyan àti ìwà ọ̀daràn tó ń foju hàn ní ẹnu ọjọ mẹ́tà yìí, láwọn ibudo ti wọ́n ko àwọn ọmọ de sí fún ìmúnilẹ́ru àti ìfìyàjẹni.

Akẹyinsi àwọn ti wọ́n fi ẹgba dá batani si lara

Láwọn ilé ti àwọn ọlọpàá tún ṣẹ̀ṣẹ̀ tú sílẹ̀ yìí, ènìyàn mẹ́tàdínláàdọjọ ní wọ́n tú sílẹ̀ nínú ìgbèkùn, ọkùnrin márùnlelọ́gọ́fà àti obinrin méjilélogun ni wọ́n gba ìtúsílẹ̀, tí àwọn mẹ́rin nínú wọn si jẹ́ àjejì láti Cameroon àti Niger Republic, pẹ̀lú ìdè àti ẹwọ̀n ti wọ́n fi de ọ̀pọ̀ wọ́n.

Agbẹ̀nusọ ilé isẹ́ ọlọpàá ìpínlẹ̀ Kaduna DSP Yakubu Sabo sàlàyé pé, ìwádìí yóò bẹ̀rẹ̀ lóri ọ̀rọ̀ náà làìpẹ́ yìí àti pé gbogbo àwọn tó gba ìtúsílẹ̀ ló ti wà ni ìpamọ.

Sabo Salaye pé, Gomina ìpínlẹ̀ Kaduna funra rẹ ló sááju ogun lọ sí ilé alaígbọ̀ràn yìí, láti mọ ǹkan to n ṣẹlẹ̀ nibẹ, tí àwọn eniyan ti wọ́n ba nibẹ̀ sì sọ pé, àwọn gba ìwé àṣẹ̀ láti maa kọ àwọn ènìyàn lẹ́kọ̀ọ́ iṣẹ́ ọwọ́.

"Obí gbogbo àwọn ọmọ náà lo mú gbogbo wọ́n wa si àkàtà wa yálà nítori pé wọn ń mu oogun oloro tàbi wọ́n ni ààrun ọpọlọ."

Igba kèji rèé ti wọn yoo tun tu awọn onde silẹ nile ọmọ alaigbọran lẹ́yìn tí ọlọpàà tú ọọdunrun miran sílẹ̀ ni inu osu kẹsan.