Adebisi Olabode: Ìjọba ìpínlẹ̀ Oyo ti fòfin de oyè Ìyá àti Babalọja
Ọrọ oyè kò yẹ ko mu ija nla bayii dani- Kọmiṣọnna
Ṣaaju asiko yii ni awuyewuye ti waye kaakiri ọja ipinlẹ Oyo lori tani iyalọja ati babalọja fun ipinlẹ Oyo lapapọ?.
Lẹyin gbogbo awuyewuye yii ni ijoba ipinlẹ Oyo labẹ akoso Gomina Seyi Makinde ti fofin de oye naa ni ipinle Oyo
- N650,000 péré ni mò ń gbà gẹ́gẹ́ bíi owó oṣù -Gomina Ọyọ
- Èdè Akurẹ àti Ibadan ni wọ́n fi fà mí léti pé ẹni re kìí 'se òṣèlú - Seyi Makinde
- APC àti PDP sọ ìgbésẹ̀ tó kàn lẹ́yìn ìdájọ́ èsì ìbò gómìnà Ọyọ
- Aṣojú Seyí Makinde lásan ní mo jẹ, òṣìṣẹ́ gbọdọ̀ bọ̀wọ̀ fún mi - Ọ̀dọ́mọdé Kọmísánà
- Irú ọjà wo ni wọ́n kò ti lè yan Ìyálọ́jà?
BBC Yoruba gbera lọ fọrọ wa awọn ti ọrọ kan lẹnuwo lati mọ ohun to n ṣẹlẹ lori ọrọ Iyalọja ati Babalọja ipinlẹ Oyo yii.
Kọmiṣọnna feto idokowo nipinlẹ Oyo, Adebisi Adeniyi Olabode ṣalaye ohun to ṣokunfa awuyewuye yii fun BBC.
O mẹnuba igbesẹ ijọba ipinlẹ Oyo ki alaafia le jọba lawọn ọja ati ki ijọba fi raaye ṣe iwadii to yẹ lori iṣẹlẹ yii.
Bakan naa ni BBC ba iyalọja ilẹ Ibadan, Alhaja Iswat Abiola Amerigun naa ba BBC sọrọ lori iṣẹlẹ yii.
Kọmiṣọna ni kete ti iwadii ijọba ba ti pari ni wọn yoo gbe igbesẹ to yẹ lori ọrọ yii.
Gbogbo igbiyanju BBC lati ba awọn igun to ku to n ja sọrọ oye yii sọrọ lo ja si pabo lasiko yii.