Headies 2019: Adekunle Gold,Teni,Burna Boy,tá ní yóò gbà àmì ẹ̀yẹ̀ olórin to fakọyọ?

Aworan awọn olorin tàkasúfèé

Oríṣun àwòrán, Facebook/tenientertainer/patorankingofficial/dekun

Àkọlé àwòrán, Ko ti daju ẹni ti ami ẹyẹ yi yoo ja mọ lọwọ
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 1

Oni loni njẹ ẹni a bẹ lọwe nidi ayẹyẹ fawọn akọrin to lamilaka lorileede Naijiria eleyi ta mọ si 'Headies'

Awọn olorin Yoruba to fi mọ akẹgbẹ wọn lorileede Naijiria yoo jijọ figagbagba lati gba ami ẹyẹ ni isọri orisirisi to fi mọ takọrin to fakọyọ ju lọ.

Ayẹyẹ naa yoo waye lalẹ oni ni ile itura Eko Hotel.

Lara awọn ti wọn ti fi orukọ wọn ṣọwọ fami ẹyẹ yi la ti ri Adekunle Gold,Patoranking, Teni 'Oba Orin' ati Burna Boy.

Loju opo Twitter awọn ololufẹ olorin kọọkan ti n ba ara wọn jiyan pe olorin tawọn nifẹ ni yoo gba ami naa.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Skip X post, 2

End of X post, 2

Igba ẹlẹkẹta re e ti wọn yoo ṣeto ami ẹyẹ yi.

Saaju asiko yi,Hip Hop World Awards ni orukọ ti wọn n pe ayẹyẹ yi ti Hip TV si jẹ agbatẹru rẹ.

Gbajugbaja elere sinima nii Nancy Isime ati olorin raapu Reminisce ni yoo ṣe atọkun eto naa ti yoo waye lalẹ oni tii ṣe ọjọ Abamẹta ọjọ kejidinlogun oṣu Kẹwa.