Russia-Africa summit: Wo àdéhùn méje tí Buhari ṣe pẹ̀lú ilẹ̀ Russia

Oríṣun àwòrán, NIGERIA PRESIDENCY
Aarẹ orilẹ-ede Naijiria, Muhammadu Buhari wa lara orilẹ-ede mẹrindinlaadọta ti wọn wa ni ibi ipade ijiroro laarin orilẹ-ede to wa ni Afirika ati Russia.
Buhari lasiko to n ba Aare orilẹ-ede Russia, Vladmir Putin sọrọ, pinnu lati rii wi pe ibasepọ to dan mọran wa laarin orilẹ-ede mejeeji.

Oríṣun àwòrán, NIGERIA PRESIDENCY
Aarẹ mejeeji pinnu lati ri wi pe wọn pari awọn akanṣe ti wọn ti bẹrẹ lorilẹ-ede Naijiria paapaa eleyii to niiṣe pẹlu ẹka epo rọọbi ni Naijiria.
- Iléeṣẹ́ Instagram wọ́gilé App "Augmented Reality filters" lórí ẹ̀rọ rẹ̀
- Ìgbẹ́jọ́ Naira Marley sún síwájú bí àwọn agbẹjọ́rò ń jà sí àga ìjókòó
- Ogun flood: ọ̀pọ̀ àwọn olùgbé agbegbe yii ti fi iṣẹ́ sílẹ̀ nítorí wọn kò lè jáde
- À ń gbé ìjọba ìpínlẹ̀ Ọyọ lọ si ilé ẹjọ- Ẹgbẹ́ Fulani darandaran
- Seun Egbegbe lo ọdún méjì àti oṣù méje lẹ́wọ̀n láì tìí san béèlì rẹ̀
- 'Àwọn ti Micra ló jẹ̀bi rògbòdìyàn awakọ̀ tó wáyé lánàá n'Ìbàdàn'
- Kí ni àwọn olórí Áfíríkà ń wá lọ sí Russia?
Ọrọ karakata ati idokowo, eto aabo ati iranwọ fun ẹka ọmọogun orilẹ-ede Naijiria.
Wo adehun meje ti Buhari se pelu ilẹ Russia
- Naijiria ati Russia ti ṣe adehun lati ri i wi pe ibaṣepọ to dan mọran wa laarin Ajọ NNPC ti Naijiria ati Ajọ Afẹfẹ Gaasi, Gazprom ti ilẹ Russia.
- Orilẹ-ede Russia tun ṣe adehun lati ri wi pe Ajaokuta Steel Rolling Mill ti wọn ti kọ silẹ lati ọdun gbooro tun dide pada.
- Bakan naa ni orilẹ-ede mejeeji ṣe adehun lati ṣe papakọ ohun ijagun ọlọgọọrọ,eleyii ti wọn yoo bẹrẹ laipẹ.
- Orilẹ-ede Russia naa tun gba lati mu ajinde ba adehun to niiṣe pẹlu iranwọ fun ikọ ọmọogun orilẹ-ede Naijiria.
- Ibaṣepọ yoo tun wa lori ọrọ eto ẹkọ ati eto ọgbin.
- Bakan naa ni awọn adari mejeeji jiroro lori ẹka to n risi eto abo ninu Ajọ Isọkan Agbaye, eleyii ti Naijiria n fẹ lati wa lara ajọ naa titi lai.













