Obateru Akinruntan: Wíwá ohun tá jẹ títí láé ló gbé wa kúrò nílé Ife

Àkọlé fídíò, Obateru Akinruntan: Wíwá ohun tá jẹ títí láé ló gbé wa kúrò nílé Ife

Yoruba ni bi ọmọ ko ba itan , yoo ba arọba, tii se baba itan.

Olugbo tilẹ Ugbo, Ọba Frederick Obateru Enitiolorunda Akinruntan ti salaye fun BBC Yoruba pe ilẹ Ugbo lo ilẹ Yoruba lapapọ.

Ọba Akinruntan sọ pe Oghonne ni orukọ ọba Ile Ifẹ n jẹ tẹlẹ, eyi to tumọ si ẹni ọwọ ati ẹni iyi ati igbakeji orisa, inu rẹ si ni wọn ti fa Ooni yọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

O ni Ikedu ni ede ti awọn Ugbo n sọ nile Ife, Ugbomokun si ni orukọ Ile Ife tẹlẹ.

Ọba alaye naa salaye pe ọna lati wa ohun tawsn yoo jẹ titi laelae lo mu awsn kuro nilu ile Ife lọ silẹ Igbo tawọn wa bayii, nibi ti awọn ti ni ọpọlọpọ ẹja ati epoo rọbi.

Bakan naa lo tun sọ nipa oju ti wọn fi n wo Moremi, to da awọn .

Amọ sa, Ooni tilu Ile Ife, Ọba Enitan Adeyeye Ogunwusi naa ti fesi pe ọpọ eeyan lo n sọ itan ti ko tọ lasiko yii amọ oun ko ni ija pẹlu ẹnikẹni, ohun ti Eledumare ran oun wa se, ni oun fẹ gbajumọ.