Àyẹ̀wò DNA ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ fún àwọn àlùfá Kátólíìkì tó bímọ

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Ajọ aladani kan ti ṣe ifilọlẹ eto ipolongo ni orilẹede Kenya lati kesi awọn obinrin to fi ẹsun kan awọn alufa ijọ Katoliki pe awọn bi ọmọ fun wọn, lati wa sẹ ayẹwo DNA.
Ajọ naa yoo ran ajọ kan to jẹ ti ijọ Katoliiki ni agbaye, ti ẹnikan ko mọ, lọwọ lati ṣe ayẹwo ẹjẹ lati le mọ boya lootọ awọn alufa naa lo fun awọn obinrin to fẹsun kan wọn loyun, ti wọn si fi bimọ.
Lẹyin ti ayẹwo ọhun ba waye ni ajọ naa yoo fi aabọ ayẹwo naa ranṣẹ si awọn alaṣẹ ijọ Katoliiki ni bonkẹlẹ, fun igbesẹ ti o ba tọ ni oju wọn.
Awọn to ba lọ fun eto ayẹwo naa yoo san owo perete.
Ọpọlọpọ igba ni ẹsun ti jade ni orilẹede Kenya pe awọn alufa ijọ katoliiki n dalẹ ẹjẹ ti wọn jẹ lati ma ni ibalopọ pẹlu obinrin, ṣugbọn ti wọn n bimọ, ti wọn si n pa awọn ọmọ naa ti .
Diẹ lara awọn ẹsun naa de ile ẹjọ, ti wọn si fi ọwọ bo awọn kan mọlẹ.













