Birth Control: Ìnàkí bímọ lẹ́yìn tí ìfẹ̀tòsọ́mọbíbí pòfo!

Oríṣun àwòrán, Twitter
Inaki kan ti bi ọmọ lorilẹede Uganda, lẹyin ti oogun ifetosọmọ bibi ti wọn lo fun kuna lati sisẹ lara ẹranko naa.
Awọn alabojuto ile awọn ẹranko naa, Ngamba Island Chimpanzee Sanctuary, to wa ni Lake Victoria, sọ wi pe iyalẹnu lo jẹ fun awọn bi inaki naa se loyun.
Awọn alasẹ naa fikun wi pe iwadii DNA n lọ lọwọ lati mọ baba inaki naa.
Inaki naa, ti orukọ rẹ n jẹ Natasha lo ti pe ọdun mọkandinlọgbọn loke eepẹ, ti wọn si fi oogun ifetosọmọbibi si ara rẹ.
Awọn alakoso naa fikun pe, oogun ifetosọmọbibi ọhun n sisẹ daradara lara awọn ọbọ to ku, sugbọn ko ye wọn bi o se yiwo lara Natasha yii.
Lẹyin ti inaki di ọlọmọ tuntun lọdun naa ni Ajọ naa wa n bere lọwọ awọn ololufẹ wọn loju opo Twitter, orukọ ti wọn yoo sọ ọmọ tutntun naa.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post








