Paternal DNA Test: Ẹ wo àlàyé lórí àyèwò DNA tó ń jà rànyìn lórí àyélùjàra

Oríṣun àwòrán, DNA
Ọrọ ṣiṣe ayẹwo lati mọ nipa ẹni to ni ọmọ yala fun iya tabi baba kii ṣe ohun tuntun mọ ni awujọ wa lode oni.
Eyi ri bẹẹ latari bi ọpọ awọn ẹri to n jade lode oni pe ọmọ ale pọ ninu awọn idile paapaa bi ọpọlọpọ baba ṣe n mọ pe awọn kọ ni awọn ni ọmọ ti awọn ti n tọ lati kekere.
Ọkan-o-jọkan awọn iṣẹlẹ yii lo maa n gbin ibẹru sọkan awọn eeyan ti wọn si maa n fẹ ṣe ayẹwo awọn ọmọ wọn lati fidi rẹ mulẹ pe awọn lo bi awọn ọmọ wọn.
Awọn iṣẹlẹ yii maa n fa ki ọpọlọpọ ariyanjiyan waye lori ayẹwo DNA, ti o ma n safihan ẹni to jẹ baba ọmọ tabi, ibaṣepọ laarin eniyan meji lori ayelujara.
Nitori naa ni a ṣe bere ibeere yii lọwọ Dokita onimọ iṣegun ati adari ẹka itọju kidinrin ni fasiti ẹkọ imọ iwosan ni ipinlẹ Ondo, UNIMED, Ayodeji Akinbodewa lori alaye kikun nipa ohun ti wọn n pe ni ayẹwo DNA ati bi o ṣe se pataki si.
Bakan naa ni dokita nipa obinrin, Micheal Gbala naa salaye ni ẹkunrẹrẹ ohun ti ayẹwo DNA tunmọ si.
Kini ayẹwo DNA? bawo lo ṣe ṣe pataki si?
Ayẹwo DNA ni ayẹwo ti a n se lati mọ boya Baba loni ọmọ to wa ninu oyun, tabi eleyii ti wọn bi saye.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
A maa n lo ayẹwọ ara to wa ninu ẹjẹ ni wọn n pe ni DNA, ohun ni awọn ẹya ti ọmọ to ba wa ninu oyun maa n jogun lati ara baba ati iya rẹ.
Bakan naa ni DNA tunmọ si ohun to sọ iru eniyan ti eniyan jẹ lati inu ẹyin iya rẹ ati atọ baba rẹ.
DNA ni asopọ to mu eniyan jade lẹyin ti eniyan ba ti mu ẹjẹ ati atọ lara awọn obi rẹ. ohun ni o ma n safihan ohun to gba ni ara awọn obi rẹ.
Nitori naa ni awọn ibatan ṣe n jọ ara wọn nitori wọn n mu eroja kan naa lara awọn obi wọn, nitori ara ọkunrin ati obinrin ni ọmọ ti n jade.
Awọn wo ni a n ṣe ayẹwo DNA fun?
Dokita Ayodeji Akinbodewa sọ wi pe ko si ẹni ti ko le e ṣe ayẹwo DNA lati le mọ ibi to ti ṣẹ wa.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Dokita Akinbodewa ni nitori kii ṣẹ awọn ayẹwọ ti a maa n se loore koore, igba ti a maa n ṣe e ni lati mọ iru ẹni ti eniyan jẹ, abi ibi ti o ti ṣẹ wa.
Ẹni to ba ti fi atọ silẹ lo ni ibi ti ọmọ ti san wa, nitori naa Baba, ọmọ, iya lẹ ṣe e lati fi da ara wọn loju.
Tabi boya iran abi ibatan to ti sọnu, ti wọn si ṣẹṣẹ ri ara wọn, ti wọn si fẹ mọ wi pe loootọ ni awọn jẹ ibatan.
A tun le se ti wọn ba fẹ mọ ẹni to fun eniyan loyun, ti ọkunrin ba kọ ọmọ.
A le ṣe fun ọmọ ninu ọyun, wẹrẹ ti wọn ba bii, abi igbakugba ti eniyan ba fẹ sẹ.
Ti eniyan ba fẹ ṣe e fun ara rẹ, o le e ṣe lai gba aṣẹ ẹlọmiran, amọ ti o ba ti n kan ọmọ tabi iya o gbọdọ gba aṣẹ lọwọ baba tabi iya ọmọ naa.
Njẹ ayederu ayẹwo DNA wa?
Ni ọpọlọpọ igba, ayẹwo DNA kii puro rara nitori bi o ba ṣe jẹ, ni yoo gbe jade kedere.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nitori ẹya ara inu ẹjẹ eniyan ni wọn n lo, o ṣoro ki ara eniyan gbe esi ti ko yẹ jade.
Nitori o nira lati ku giri lo ṣe ayẹwo DNA, awọn eniyan mAa n kọkọ ṣe idanilẹkọọ ki wọn to lọ ṣe e.
Kini awọn ofin to rọmọ ṣiṣe ayẹwo DNA?
Ko ye ki ede aiyede wa lori ọmọ, ti ọkọ ati iyawo ba ṣe olootọ laaarin ara wọn.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Amọ, ti ko ba si idaniloju, ki o to di nnkan to n gbe wọn lọkan soke tabi ibanujẹ, o dara kii wọn tete ṣe ayẹwo ẹjẹ DNA.
Nitori kii ṣe ohun ti wọn n ṣe lojoojumọ, ọkọ ati iyawo nilo lati fi ọwọ si ṣiṣe ayẹwo DNA ọmọ, ti wọn ko ba ni ohun ti wọn n fi pamọ.
Awọn ẹlomiran maa n ṣe lati rinrinajo lọ si ile okeere, ti wọn si nilo ami idaju wi pe awọn lo ni ọmọ, nitori naa wọn ko nilo ipẹjọ lati ṣe.
Ṣe ayẹwo DNA ko wọngogo fun awọn eniyan lati ṣe?
Ayẹwo DNA ati ayẹwo arun Coronavirus fi ara jọ ara, nitori kokoro naa ni a n pe jade lati mọ boya o wa ninu ara.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
Nitori naa bi ayẹwo arun Coronavirus ṣe wọn ni awọn ibi kọọkan nitori ko wọpọ, naa lo ṣe ri fun .
Awọn ibi ti wọn ti n ṣe ni Naijiria ko pọ, nitori naa owo rẹ ko kere.
Dokita Akinbodẹwa wa rọ awọn eniyan lati ṣe otitọ si ara wọn,ki wọn si kọ lati maa dariji ara wọn.
Bakan naa ẹni to ba fẹ ṣe ayẹwọ DNA gbọdọ kọkọ ṣe idanilẹkọọ, ko si mọ iru ipalara to le ti ẹyin ayẹwo naa jade.












