Vaccine rumours debunked: Àwọn ìròyìn òfegè nípa abẹ́rẹ́ àjẹsára Covid-19

Oríṣun àwòrán, Getty Images
A ṣe agbeyẹwo awọn iroyin ofege ti awọn eeyan n gbe kiri nipa abẹrẹ ajẹsara Covid-19.
Lara awọn iroyin ofege naa ni pe awọn eleto ilera fẹ lo ẹrọ kọmputa ti wọn ko le foju ri si ara eeyann, ati bẹbẹ lọ.
Ayipada si DNA eeyan
Awọn iroyin kan ti n gbode lori ayelujara pe abẹrẹ ajẹsara Covid-19 lagabra lati yi DNA eeyan pada.
Ileeṣẹ iroyin BBC bere lọwọ awọn onimọ sayẹnsi nipa ibẹru awọn eeyan lori ọrọ yii, awọn onimọ naa si sọ pe ko si ohun to jọ bẹ.
Lara awọn abẹre ajẹsara ti wọn ṣẹṣẹ gbe jade ni eyii ti ilẹ UK ti fọwọ si lati ileeṣẹ apoogun Pfizer/BioNTech.
Onimọ kan lati fasiti Oxford, Ọjọgbọn Jeffery Almond sọ pe abẹrẹ yii ko le ṣayipada si DNA eeyan.

Wọn ni bi abẹrẹ naa yoo ṣe ṣiṣẹ ni pe, yoo pese eroja aṣara loore, eyii ti yoo le gbena woju kokoro arun Coronavirus ninu agọ ara.
Ninu oṣu karun un ọdun 2020 ni fidio kan gbode lori ayelujara, eyii to n ṣafihan pe abẹrẹ ajẹsara yoo ṣe paṣipaarọ DNA eeyan, amọ awọn onimọ naa ti sọ pe ko ri bẹ.

Oríṣun àwòrán, Adam Gault
Ki wọn to gbe abẹreẹ ajẹsara Covid-19 jade, awọn onimọ ṣiṣẹ tọsan-toru lati ri daju pe ko ṣe ijamba si ara gbogbo awọn to ba gba.
Ẹrọ kọmputa Bill Gates ti eeyan ko le foju ri
Iroyin ofege ti a o tun mẹnuba ni ti ẹrọ kọmuter to kere jọjọ, ti eeyan ko le foju ri ti wọn sọ pe baba olowo Bill Gates wa nidii rẹ.
Ajọ Bill ati Melinda Gates ti sọ fun BBC pe awọn ko ṣe ẹrọ kankan lati fi sinu agọ ara eeyan lati le mọ ibikibi ti wọn ba wa ni gbogbo igba.

Iroyin yii gbinlẹ loṣu Kẹta ọdun 2020, nigba ti Bil gates sọ ninu ifọrọwerọ kan pe wọn yoo lo ẹrọ kọmputa lati mọ awọn to ti moribọ lọwọ arun naa.
O ni kii ṣe pe wọn yoo gbin kọmputa ti eeyan ko le foji ri si agọ ara eeyan lati mọ ibi ti wọn wa ni gbogbo igba.
Bill Gates sọ pe irọ nla gbaa ni iroyin ọhun.
O ni ẹrọ ti oun n sọ nipa rẹ yoo dabi ami tatuu lara eeyan ti ko ni han si gbangba.
O ṣalaye pe ki awọn eeyan ma ṣe foya nitori ileeṣẹ oun ko gbe ẹrọ kọmputa ti awọn kan n sọ nipa rẹ jade.
Lilo oyun inu fun abẹrẹ ajẹsara Covid-19
A tun ti ri awọn iroyin kan to sọ pe ẹdọforo oyun ti wọn ṣẹ yoo jẹ ọkan lara awọn eroja ti wọn yoo fi po abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ọhun.

Nigba to n sọrọ lori iroyin yii, Ọmọwe Michael Head, lati fasiti Southampton ni irọ nla gba ni.
Ọmọwe David Mathews ni fasiti Bristol naa ni wọn lo awọn cẹẹli atọwọda nigba ti wọn n po abẹrẹ ajẹsara naa pọ, ṣugbọn kii ṣe ti oyun ti wọn ṣẹ.
Iwosan Covid-19
A ti ri awọn iroyin kan lori ayelujara to sọ pe eeyan ni anfani ida 99.9% lati gbawosan lọwọ Covid-19.
Iroyin naa tẹsiwaju pe o san ki eeyan ni Covid-19, nitori o lanfaani lati ri iwosan gba ju ki o gba abẹrẹ ajẹsara arun naa lọ.
Oluṣiro agba ni fasiti Oxford, Jason Oke sọ pe ida 99.0% awọn to lugbadi Covid-19 lo gbawosan.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
To n tumọ si pe ninu eeyan ẹgbẹrun mẹwaa to ba ni, ọgọrun ninu wọn ni yoo ku, iye naa si pọ ju ohun ti iroyin naa sọ lọ.
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ awọn to lugbadi arun naa lo ri iwaosan gba pada, ṣugbọn ninu wọn lo maa n lo ọpọ ọsẹ ninle iwosan, ti awọn miran si maa n wa ni ẹsẹ kan aye, ẹsẹ kan ọrun.
Pẹlu gbogbo ohun ti ẹ ti ka yii, a lero pe ẹ le gbe igbesẹ to dara lori abẹrẹ ajẹsara naa to ba ti wa ni arọwọto yin.














