Aisha Buhari: Aya Ààrẹ Buhari ké sí àwọn aya gómìnà pé kí wọ́n lọ paná ìdàrúdàpọ̀ ágbègbè kóówá

Aishat

Oríṣun àwòrán, @Aishat

Aisha Buhari rọ àwọn aya gómìnà láti gbárùkù ti ètò àláafíà láwùjọ wọń.

Iyawo Aarẹ, Hajia Aisha Buhari, ti rọ awọn aya gomina ni Naijiria lati ṣe koriya fawọn obinrin, ki wọn si fọwọsowọpọ pẹlu awọon ọdọ atawọn obinrin ẹgbẹ wọn ki alaafia le jọba ni Naijiria.

Aisha lo sọ ọrọ naa nibi idanilẹkọ kan lori ọna ti alaafia le gba jọba lawujọ pẹlu ifọwọsowọpọ awọn ọdọ atawọn obinrin lẹyin ajakalẹ arun Covid-19.

Aya Aarẹ, ti olubadamọran agba fun Aarẹ lori ọrọ awọn obinrin, Hajo Sani, ṣoju fun sọ pe, Covid-19 ti da rogbodiyan silẹ kaakiri agbaye eyi to n ṣokunfa oriṣiriṣi ifẹhonuhan ati iwa ipa lawujọ, paapa si awọn obinrin.

Aisha Buhari ni awọn ọmọde atawọn obinrin ni atubọtan arun naa yoo pa lara ju nitori aini anfani si eto ẹkọ to yanranti ati eto ilera to peye.

Ninu atẹjade kan lati ọọfisi iyawo Aarẹ, o ni "ojuṣe wa ni gẹgẹ bi ẹni to wa lori ipo adari lati gbaruku ti awọn obinrin ati awọn ọdọ fun igbedide alaafia lawujọ."

Minisita fun ọrọ awọn obinrin, Dame Pauline Tallen, ti amugbalẹgbẹ rẹ, ọmọba Dame Pauline Tallen ṣoju fun sọ pe kii ṣe akoko yii lo yẹ ki awọn dakẹ nitori awọn ohun to n ṣẹlẹ kaakiri agbaye.

Àkọlé fídíò, Promise Akinlade: ọmọ ọdún mọ́kànlá tó ń fi ìlù dárà bíi àgbàlagbà sọ̀rọ̀ nípa tálẹ́ǹtì rẹ

O ni ileeṣẹ to n ri si ọrọ awọn obinrin labẹ oun yoo ṣe gbogbo ohun to yẹ lati ri pe alaafia wa lawujọ, o si jẹ eyii to ṣe é gbe fun gbogbo eeyan.

Tallen rọ gbogbo ọmọ Naijiria gẹgẹ bi ẹnikankan lati mu ọrọ ẹkọ awọn ọmọ obinrin ni ọkunkundun.

Iyawo gomina ipinlẹ Ekiti, to tun jẹ alejo pataki nibi idanilẹkọ naa, Erelu Bisi Fayemi mẹnuba ojuṣe awọn aya gomina nipa idagbasoke awujọ.

Lara awọn eeyan Pataki to wa nibi idanilẹkọ naa ni aṣoju ilẹ Gẹẹsi si Naijiria nipa eto ọrọ aje, Helen Grant, ati alaga ẹgbẹ awọn ọmọ Naijiria nilẹ okere, Abike Dabiri-Erewa.