ASUU strike: Mi ò tíì lè sọ ní pàtó ìgbà tí a ó fòpin sí ìyanṣẹ́lódì wa - Aarẹ ASUU

ASUU

Oríṣun àwòrán, @ASUU

A kò ní padà sílé ìwé àyàfi t́i ìjọba bá san owó oṣù tó jẹ wá - ASUU

Ẹgbẹ awọn olukọ fasiti ni naijiria, ASUU, ti sọ pe awọn ko ni pada sẹnu iṣẹ ayafi ti ijọba apapọ ba san gbogbo owo to jẹ awọn olukọ naa.

Aarẹ ẹgbẹ ọhun, Ọjọgbọn Biodun Ogunyemi lo sọ be fun ileeṣẹ iroyin abẹle Punch lọjọ Aiku.

O ni ki ijọba apapọ má reti ki awọn olukọ fasiti naa pada sile iwe titi di igba to ba san owo to jẹ wọn.

Ti ẹ ko ba gbagbe, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun 2020, ni ASUU gba pe awọn yoo fopin si iyanlodin ọlọjọ gbọọrọ ti wọn gunlẹ lẹyin ti ijọba apapọ ni oun yoo yọnda 70 biliọnu fun wọn gẹgẹ bi owo ti oun jẹ wọn ṣaaju.

Àkọlé fídíò, Ojú mi ti rí lọ́pọ̀ lọpọ̀, àmọ́ mo dúpẹ́ pé mo ti pé ọdún márùn ún lórí oyé- Ooni

Ṣugbọn Ogunyemi ni ẹgbẹ naa ṣi n ṣe ipade lọwọ, wọn si n reti ki ijọba mu ileri rẹ ṣe nipa sisan owo to jẹ wọn.

O ni "a ṣi n ṣepade lọwọ ako si tii pari ipade na, ṣugbọn a o fi esi ababọ ipade wa lede fun gbogbo eeyan titi ipari ọsẹ yii."

"Ijọba ṣeleri pe oun yoo san owo awọn oṣiṣẹ wa, a ṣi n reti ko gbe igbesẹ lori ileri rẹ ṣugbọn a ko tii gbọ nkankan."

Ogunyemi sọ siwaju si pe "ijọba ko le reti ki a kan dede pada sile iwe bẹẹ lai tii ri owo to jẹ wa gba."

Aarẹ ẹgbẹ naa ṣalaye pe ti ijọba ko ba san owo naa ni akoko ti gbendeke ti wọn fun ba ti pari, awọn yoo gbe igbesẹ to kan.

O wa pari ọrọ rẹ pe oun ko tii le sọ ni pato akoko ti ASUU yoo fopin si iyanṣẹlodi naa.

Àkọlé fídíò, Cancer: Àṣe ara mi ni iso ti n run gbogbo bí mo ṣe n ṣèrànwọ́ lórí jẹjẹrẹ