Ghana elections 2020: NDC ní òun yóò kéde ìgbésẹ̀ tó kàn láìpẹ́

Ghana

Oríṣun àwòrán, facebook

Ẹgbẹ oselu alatako gboogi lorilẹede Ghana ti fọnmu lori abajade esi ibo aarẹ ti wọn kede rẹ nirọlẹ ọjọru.

Ẹgbẹ oselu alatako naa faake kọri lati faramọ pe aarẹ to wa lori oye, Nana Akufo Ado lo jawe olubori ninu ibo naa, eyi to ni o kun fun magomago ati ọpọ aisedeede.

Ẹgbẹ oselu National Democratic Congress NDC naa ni laipẹ ni oun yoo kede igbesẹ to kan lori ọrọ yii.

Aarẹ Nana Akufo Addo lo ni ida ibo mọkanleladọọta o le diẹ ninu ọgọrun, ninu ibo aarẹ to waye lorilẹede Ghana lọjọ Aje, ti alatako rẹ si ni ida ibo mẹtadinlaadọta ati diẹ ninu ọgọrun.

Idije dupo aarẹ ni orilẹ-ede Ghana

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Awọn onwoye eto idibo labẹle ati lẹyin odi si lo ni ko si apade alude kankan ninu ibo naa, kedere lo han fun araye bo se lọ.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nigba to n sọrọ akọsọ lẹyin to wọle fun saa keji naa, Aarẹ Nana Akufo Addo beere fun irẹpọ laarin awọn ọmọ orilẹede naa, to si tun jẹjẹ lati mu agbega ba igbe aye wọn.