Coronavirus updates: Gómìnà ìpínlẹ̀ Oyo, Seyi Makinde, ti gba abẹ́rẹ́ àjẹsára COVID-19

Oríṣun àwòrán, @seyiamakinde
Gomina ipinlẹ Oyo, Amojuẹrọ Seyi Makinde ti darapọ mọ awọn gomina to ti gba abẹrẹ ajẹsara Covid-19 ni Naijiria.
L'Ọjọru ni gomina ọhun gba abẹrẹ naa to n gbogun ti aarun Corona eyii ti ileeṣẹ apoogun AstraZaneca ṣe.
Akọwe ẹka eto ilera alabọde nipinlẹ Ọyọ, Dokita Muideen Olatunji lo fun Makinde ni abẹrẹ naa ni ilu Ibadan ti i ṣe olu ilu ipinlẹ ọhun.
Lẹyin ti Gomina Makinde gba abẹrẹ tirẹ tan lo siṣọ loju lilo rẹ fun awọn eeyan ipinlẹ Ọyọ, bẹrẹ lati ori awọn oṣiṣẹ eto ilera.
Ninu oṣu Kẹta ọdun 2021 yii ni wọn ko abẹrẹ ajẹsara naa wọle si Naijiria labẹ eto Covax.
- Wo àwọn ọ̀rọ̀ tó ki pọ́pọ́ tí Lateef Adedimeji fi kọrin ọjọ́ ìbí fún Adebimpe Oyebade "Onítèmi"
- Ẹnikẹ́ni tó bá fa wàhálà míì lẹ́yìn rògbòdìyàn ọ̀rọ̀ Hijab tó wáyé n'Ilorin yóò fojú winá òfin - AbdulRazaq
- "Afòjúsùn ẹgbẹ́ òsèlú APC ni láti ṣèjọba Naijiria fún ọdún méjìlélọ́gbọ̀n"
- Sùkẹ̀! Ọ̀rọ̀ òṣèlú ni gbogbo ẹ tí Akeredolu ṣe tako ìdásílẹ̀ Oduduwa Nation - Banji Akintoye
Bi ẹ ko gbagbe, Ngong Cyprian ni ẹni to kọkọ gba abẹrẹ naa ni Naijiria niluu Abuja.
Lẹyin naa ni Aarẹ Muhammadu Buhari ati igbakeji rẹ, Yemi Osibajo gba abẹrẹ ti wọn loju gbogbo ọmọ Naijiria lati ru awọn ara ilu soke lati gba abẹrẹ ọhun.
Apapọ awọn to ti lugbadi Covid-19 ni Naijiria ti le ni 162,000, awọn 148,530 moribọ lọwọ arun naa nigba ti eeyan 2,031 ti dagbere faye.
- Èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti náwó yàlàyòlò lábẹ́ òfin, ṣùgbọ́n ọ̀nà tí ìjọba lè gbà tojú bọ owó rẹ rèé
- Ẹ̀yà Yorùbá ti fara ṣiṣẹ́ púpọ̀ fún Naijiria, nítorí nàá à kò le déèdé sọ pé a fẹ́ kúrò - Àgbààgbà Yorùbá
- A ò pe Sunday Igboho lọ́mọ alè Yorùbá o àmọ́, a ó jọ́ bèrè lọ́wọ́ Alálẹ̀ Ibadan àti gbogbo Yorùbá ni - Olubadan
- 'Ohun táá ṣe rèé bẹ́ẹ bá kọ̀ láti wá gbé àwọn òkú yín kúrò ní Mọ́ṣúárì wa'
- Mo gbàdúrà kí n má kábàmọ́ fífagilé ẹjọ́ pẹ̀lú àwọn tó jí àwọn ìbejì mi gbé nílé ẹjọ́ - Akeugbagold













