Ẹgbẹ́ APC ní láti wà lórí oyè kí ìjọba tiwantiwan lè fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa - Mai Mala Buni

Oríṣun àwòrán, @GarantiBrah
Alaga ẹgbẹ oṣẹlu APC, to tun jẹ gomina ipinlẹ Yobe, Mai Mala Buni ti sọ pe afojusun ẹgbẹ ọhun ni lati tukọ ijọba Naijiria fun ọdun mejilelọgbọn.
Mai Mala lo sọ ọrọ naa lasiko to n yan igbimọ ẹlẹni mọkanlelọgọta kan ti yoo ṣeto apero ẹgbẹ ọhun to n bọ lọna ni ọọfisi ẹgbẹ naa to wa niluu Abuja.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, ẹgbẹ eṣelu APC ni lati wa lori ipo fun ọpọ ọdun ki ijọba tiwantiwa to ti bẹrẹ lati ọdun 2015 le fẹsẹ mulẹ daadaa.
- Sùkẹ̀! Ọ̀rọ̀ òṣèlú ni gbogbo ẹ tí Akeredolu ṣe tako ìdásílẹ̀ Oduduwa Nation - Banji Akintoye
- Èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti náwó yàlàyòlò lábẹ́ òfin, ṣùgbọ́n ọ̀nà tí ìjọba lè gbà tojú bọ owó rẹ rèé
- Wo àwọn ọ̀rọ̀ tó ki pọ́pọ́ tí Lateef Adedimeji fi kọrin ọjọ́ ìbí 23 fún Adebimpe Oyebade "Onítèmi"
- Ẹ̀yà Yorùbá ti fara ṣiṣẹ́ púpọ̀ fún Naijiria, nítorí nàá à kò le déèdé sọ pé a fẹ́ kúrò - Àgbààgbà Yorùbá
O ṣalaye pe awọn gbe igbimọ naa kalẹ ki wọn le mu ipinu naa ṣẹ.

Oríṣun àwòrán, @BashirAhmaad
Lara awọn to wa ninu igbimọ ọhun ni awọn gomina, minisita, ṣenatọ atawọn agbagba oloṣelu, eyii ti gomina ipinlẹ Jigawa, Muhammadu Badaru Abubakar ṣe olori wọn.
- Bí òkú ṣe máa ń bàjẹ́ ní Mọ́ṣúárì tẹ́ẹ ò bá san owó ìtọ́jú fáwọn olùtọ́jú òkú rèé
- A ò pe Sunday Igboho lọ́mọ alè Yorùbá o àmọ́, a ó jọ́ bèrè lọ́wọ́ Alálẹ̀ Ibadan àti gbogbo Yorùbá ni - Olubadan
- Mo gbàdúrà kí n má kábàmọ́ fífagilé ẹjọ́ pẹ̀lú àwọn tó jí àwọn ìbejì mi gbé nílé ẹjọ́ - Akeugbagold
- Agbébọn yabo ílé ìtajà ìgbàlódé, èèyàn mẹ́wàá bá d'èrò ọ̀run
Lati igba ti wọn ti yan gomina ipinlẹ Yobe yii gẹgẹ bii alaga fidihẹ ẹgbẹ APC ni awọn awuyewuye kan ti n waye ninu ẹgbẹ naa.
Ṣugbọn o ti n gbiyanju lati ri daju irẹpọ wa ninu ẹgbẹ ọhun.









