Kayode Fayemi 2023 ambition: Mo ṣì níṣẹ́ púpọ̀ láti ṣe ní ìpìnlẹ̀ Ekiti ká tó máa sọ̀rọ̀ọ̀ ìbò ààrẹ 2023

Gomina Kayode Fayemi

Oríṣun àwòrán, kfayemi

Gomina ipinlẹ Ekiti to tun jẹ adari gbogbo awọn gomina orilẹede Naijiria, Kayode Fayemi ti fesi lori gbogbo ohun tawọn eeyan n sọ pe o fẹ du ipo aarẹ.

Gẹgẹ bi ọpọlọpọ ọmọ Naijiria ṣe maa n fọ lesi lori awọn nkan ti Fayemi ba sọ lasiko yii pe aluwala olongbo rẹ, ọgbọn ati ko ẹran jẹ lọdun 2023 gẹgẹ bi aarẹ ni.

Ẹwẹ, lori eto ifọrọwanilẹnuwo kan to ṣe pẹlu ileeṣẹ iroyin Channels tv kan "Hard Copy ti wọn ṣe lọjọ Ẹti, ọgbẹni Fayemi ni oun ṣi n dupẹ lọwọ awọn eeyan oun nipinlẹ Ekiti pe wọn nigbagbọ ninu oun lati di gomina wọn.

Fayemi n da atọkun lohun lai fẹ mẹnu ba a boya oun fẹ dije du ipo aarẹ lọdun 2023 abi bẹẹ kọ, ṣe lo ni iṣẹ ṣi ku.

Àkọlé fídíò, 'Èmi àti ìyàwó mi ti ń gbé pọ̀ nínú ìgbéyàwó wa fún 60 years', ẹ wá kọ́ ẹ̀kọ́ lẹ́nu àgbà méjì

Gomina Fayemi ni "ko si oloṣelu ti wọn yoo fun lanfani lati du ipo aarẹ Nainjiria ti yoo wọn ọn danu sẹyin eti.

O rẹrin keekee lati dahu si ibeere yii ti atọkun ṣaa n tiraka ko le fesi tori ko fẹ fesi sii.

"Mo n rẹrin tori gbogbo igba ni wọn maa n bi mi ni ibeere yii... mi o mọ oloṣelu kankan to mọ ohun to n ṣe ti wọn yoo fi anfani ati dari orilẹede lọ ọ ti ko ni dan an wo, amọ a o tii de bẹyẹn".

Ẹwẹ, Fayemi to jẹ ọkan pataki lara awọn to ri aridaju ituleka igbimọ amuṣya ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress kọ lati sọ oju abẹ nikoo boya oun yoo gbe apoti ibo aarẹ lọdun 2023.

Ṣugbọn Fayemi ni pipari saa oun gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ekiti gangan ni oun gbajumọ eyi ti yoo pari losu kẹwa ọdun 2022.

Àkọlé fídíò, Báa ṣe lọ́pọlọ tó, ẹnu Yorùbá ò kò, ọgbọ́n táa gbúdọ̀ dá rèé - Ìpàdé àgbààgbà Yorùbá n'Ibadan

"Mo ni iṣẹ lọwọ, ka si ma parọ mo dupẹ gidi lọwọ awọn eeyan ipinlẹ Ekiti ti wọn fun mi ni anfani lati dari ipinlẹ naa lẹẹmeji mo dẹ ṣi ni ọpọlọpọ nkan ti mo fẹ ṣe nibẹ".

Fayemi ni nitorina, ọjọ iwaju yoo tọju ara rẹ atipe ohun ti oun mọ bayii ni pe, iṣ wa lọwọ oun bayii.

Nigba to n da si ọrọ lilo Hijab lawọn ileewe ẹlẹsin to n fa rogbodiyan ni ipinlẹ Kwara, gomina Kayode Fayemi ni o yẹ ki orilẹede Naijiria fa ọwọ ẹlẹsinmẹsin to duro gbọingbọin soke wa silẹ patapata.

"O ṣeeṣe ko jẹ ọwọ iṣẹ ati idamu kan lo n fa iru nkan to n ṣẹlẹ yii".