Lagos one-day governor: Gómìnà Sanwo-Olu gba pẹ̀lú gómìna ọlọ́jọ́ kan fún ìpínlẹ̀ Eko dámọ̀ràn lórí ìdàgbàsókè ètò ẹ̀kọ́

Gomina Sanwo-olu pẹlu Ẹniọla Ajala, gomina ọlọjọ kan ni ipinlẹ eko fun ọdun 2021

Oríṣun àwòrán, Twitter/ babajide sanwo-olu

Gomina Babajide Sanwo-Olu ti ipinlẹ Eko ti gba gomina tuntun fun ipinlẹ naa, Omidan Ẹniọla Ajala lalejo lọfisi rẹ.

Omidan Ẹniọla Ajala ni gomina ọlọjọ kan fun ipinlẹ Eko lẹyin to gbegba oroke nibi idije 'Ta n mọ ọ?' New Era Spelling Bee Competition fawọn akẹkọọ ileewe girama ni ipinlẹ naa.

Lasiko ipade rẹ pẹlu Omidan Ajala atawọn ọmọ igbimọ iṣejọba rẹ, gomina Sanwo-Olu ni idagbasoke eto Ẹkọ ko ni rẹyin ninu eto idagbasoke isọdọtun ti iṣejọba oun gbe kari eyi to pe ni 'THEMES agenda'

Gomina ọjọ kan.

Oríṣun àwòrán, Lagos state Government

Àkọlé fídíò, 'Èmi àti ìyàwó mi ti ń gbé pọ̀ nínú ìgbéyàwó wa fún 60 years', láì sí ìṣòro'

O ni ijọba ipinlẹ Eko yoo tubọ maa rii daju pe ayika ikẹkọ ni ipinlẹ naa tubọ ṣi n mu ki eto ẹkọ o dun un kọ fawọn akẹkọọ.

O wa kan sara si omidan Ajala fun ijafafa, iṣọkan akin ati iduro ṣinṣin rẹ pẹlu amọran pe oun atawọn ọmọ igbimọ rẹ ko gbọdọ faye gba igbesẹ ṣiṣe akoso ipinlẹ Eko fun ọjọ kan lati ko si wọn lori to bẹẹ ti wọn yoo fi yẹsẹ kuro lojuna idagbasoke ẹkọ wọn.

Ẹniọla Ajala, gomina ọlọjọ kan ni ipinlẹ eko fun ọdun 2021

Oríṣun àwòrán, Twitter/ babajide sanwo-olu

Omidan Ẹniọla Ajala to jẹ gomina ọjọ kan ni ipinlẹ Eko fun ọdun 2021 jẹ akẹkọọ ileewe girama Lafiaji Senior High school, Lagos Island.

Awọn ọmọ igbimọ rẹ yooku ni Grace Ikhariale lati ileewe girama TinCan Island Senior High School, Tolu , to jẹ igbakeji gomina; Oluwatosin Akinbọdewa lati Iworo Ajido Senior Secondary School, Badagry ni olori ile aṣofin; Eunice Adedọtun lati Agbẹdẹ Senior School Ikorodu ni kọmiṣọna eto ẹkọ, ti Ekene Ezeunala lati Meiran Community High school jẹ alaga igbimọ tẹlekoto lori eto ẹkọ nile aṣofin ipinlẹ naa.

Ninu ọrọ rẹ lasiko to fi n lewaju ipade ọlọsọọsẹ ti igbimọ iṣakoso ijọba ipinlẹ Eko, gomina ọlọjọ kan ni ipinlẹ Eko fun ọdun 2021, omidan Ẹniọla Ajala dupẹ pupọ lọwọ gomina ipinlẹ Eko, Babajide Sanwo-Olu fun ọla, ẹyẹ ati iyi to bu fun awọn akẹkọọ to bori nibi idije 'Ta n mọ ọ?' naa.

Gomina Sanwo-olu pẹlu Ẹniọla Ajala, gomina ọlọjọ kan ni ipinlẹ eko fun ọdun 2021

Oríṣun àwòrán, Twitter/ babajide sanwo-olu

Bakan naa lo gboriyin fun gomina Sanwo-Olu lori bi o ṣe moju to ọrọ ajakalẹ arun COVID-19 ni ipinlẹ naa, to si rọ awọn akẹkọọ lati maa foju si ẹkọ wọn ki wọn lee bori awọn ipenija gbogbo ni ọna wọn.

Bakan naa ni 'gomina' Ẹniọla Ajala ke si gomina Sanwo-Olu pe ko tubọ pese awọn ohun elo amayedẹrun lawọn ileewe tawọn akẹkọọ to bori idije naa ti jade wa to si tun rọ ijọba lati ṣeto ẹbun to jọju fun awọn obi oun, to gboriyin fun pẹlu bi wọn ṣe tọ ọ ni ọna gbogbo to yẹ.