Fuel price hike: Àjọ elépo rọ̀bì, NNPC ní kó sáyé fífi owó kún owó epo bẹntiró báyìí

Oríṣun àwòrán, others
Ajọ elepo rọbi lorilẹede Naijiria, NNPC ti rọ awọn eeyan orilẹede Naijiria lati lọ fi ọkan wọn balẹ na o nitori ko si ohun kan to tii yẹ, tabi sun owo ori epo bẹntiro kuro ni iye to wa tẹlẹ.
Ajọ NNPC ni ijiroro ati ifikuluku n lọ lọwọ pẹlu awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ atawọn alẹnulọrọ lẹka naa, o si di igba ti eyi ba pari ki igbesẹ kankan to lee waye.
- Kò sí olóṣèlú tí wọ́n fi tọ́ lẹ́nu wò pé kó di ààrẹ Naijiria ní 2023 tí kò ni tọ ọ́ lá - Fayemi
- Gómìnà Sanwo-Olu gba gómìna tuntun fún ìpínlẹ̀ Eko lálèjò
- Akintoye sá lọ Amẹrika lásìkò ìjọba ológun, ó wá fẹ́ da Naijiria rú báyìí - Akeredolu
- Kí ló lè fàá kí Yomi Fabiyi àti PA rẹ̀ máa fẹnu ko ara wọn l'ẹ́nu?
- Ọwọ́ agbófinró tẹ obìnrin tó gbé 'cocaine' sínú ojú ara rẹ̀ l'Abuja
- Ìdí tí NIN rẹ fi ṣe pàtàkì láti forúkọsílẹ̀ fún ìdánwò JAMB 2021 rèé
Ninu ọrọ to ba awọn oniroyin sọ ni ilu Abuja, adari ẹka alukoro ni ajọ naa, Ọmọwe Kennie Ọbatẹru ṣalaye pe lọwọ yii ajọ naa lo n fori rọ wahala ati ẹru kiko epo rọbi wọle sorilẹede Naijiria lati lee rii daju pe ohun amuṣagbara wa forilẹede Naijiria.
Ọmọwe Ọbatẹru ni ko si ohun to jọ fifi owo le iye ti wọn n ta epo bẹntiro tẹlẹ nitori ifikuluku to ṣi n lọ lọwọ naa ati pe wọn ti ṣeto bi iye epo tawọn araalu yoo nilo ni anito ati aniṣẹku yoo ṣe wa larọwọto lorilẹede Naijiria.
Ajọ NNPC wa rọ awọn ileepo to n da aṣẹ ara wọn pa nipa fifi kun iye owo epo bẹntiro lati lọ simọdọ ki wọn maa si da alaafia ẹka epo rọbi lorilẹede Naijiria ru.
Bakan naa lo rọ awọn ọntaja epo atawọn onimọto tabi ọlọkada pe ni ki wọn ye ko tabi ra epo pamọ to ni ireti pe yoo wọn sii laipẹ.









