Lagos police: Wọ́n ti gba'ṣẹ́ lọ́wọ́ ọlọ́pàá ọ̀mùtí

Oríṣun àwòrán, Lagos State Police Command
Ọlọ́paa kan Kadima Useni to di olokiki nigba ti fidio ṣe afihan rẹ nibi to ti mu ọti yo ni agbegbe Akowonjọ, Dopemu ni ilu Eko ni ọga agba ọlọpaa Ibrahim Idris ti paṣẹ pe ki wọn gba iṣẹ lọwọ rẹ.
Atẹjade kan lati ọwọ agbẹnusọ ile-iṣẹ ọlọpaa Ipinlẹ Eko Chike Oti ni Ọjọru ṣalaye wipe ibudo Force Squadron 22 ni Ikeja ni Useni ti n ṣiṣẹ.
O ni nigba ti wọn fi ọrọ wa ọlọpaa naa lẹnu wo, o jẹwọ wipe ootọ ni pe oun lo wa ninu fidio naa, ni wọn ba ṣe idajọ ranpẹ ti awọn ọlọpaa fun un, ti wọn si gba aṣọ lọrun rẹ.
Àwọ́n ìròyìn mìíràn tí ẹ lé nífẹ̀ẹ́ sí:
Ẹwẹ, ọga ọlọpaa ni Ipinlẹ Eko, Imohimi Edgal ti paṣẹ pe ki wọn ti gbogbo ile ọti to wa ni agbegbe ibudo ọlọpaa to wa ni Ikeja pa.
O si tun kilọ fun awọn ọlọpaa pe wọn yoo wọ gau ti wọn ba n mu ọti lẹnu iṣẹ.









