Gómìnà Dapo Abiodun fún Modupe Akintola n'íṣẹ́ ọ̀fẹ́

Esther Modupe bọ Gomina lọwọ

Gomina ipinlẹ Ogun, Ọmọọba Dapo Abiodun ti fi iṣẹ ọfẹ ta arabinrin Akintola Esther Modupe to jawe olubori gẹgẹ bi akẹkọọ to pegede ju ni ile ẹkọ akọṣẹmọṣẹ ti Ilaro lọrẹ.

Iroyin sọ pe odiwọn iye kokoo maaki 3.90 ninu kokoo maaki 4 eyi to ga ju ni arabinrin Akintola gbe jade nile ẹkọ naa.

Kete ti Modupe ba ti pari agunbanirọ rẹ ni yoo bẹrẹ iṣẹ yii gẹgẹ bi gomina ṣe seleri.

Ipinlẹ Ogun

Gomina Abiodun ti ipinlẹ Ogun fi eyi lede nibi ajọdun ikẹkọjade ogoji ọdun ti ile iwe giga naa lọjọru ọsẹ.

Gomina ni oun ṣe eyi lati ṣe moriya ati lati gba awọn akẹkọọ toku niyanju lati ṣe ju bẹẹ lọ tori o ni iṣejọba oun mu eto ẹkọ lọkunkundun.

"Iṣejọba wa ni ifarajin fun ṣiṣe ohun to yẹ fun eto ẹkọ ati pipese ẹkọ to yekoro fun awọn ọmọ ipinlẹ Ogun lai fi ti ipo wọn lawujọ ṣe".

Àkọlé fídíò, Mama Rainbow: Toyin Adegbola àti Razak Olayiwola ní ìyá rere àti àwòkọ́ṣe gidi ní

O ni igbagbọ awọ́n ni pe ọmọ to ba kawe rẹ daadaa ko kan ni wulo fun ara rẹ nikan bikoṣe ko lọwọ si idagbasoke ipinlẹ rẹ.Gomina Abiodun fi anfani eto yii kede pe iṣejọba oun ti yanju iṣoro ile iwe akọṣẹmọṣẹ Moshood Abiola ati ti wahala to n suyọ lori ile iwe olukọ̀ni Tai Solarin(TASCE) to wa ni Omu Ijebu ti wn si ti ṣagbekalẹ ibudo pataki kan fun eto ẹkọ ni ipinlẹ naa.