Katsina Den: Ilé mìíràn tí wọn ti n fi ìyà jẹni ni Olọpàá ti rí

Ile Iwe Kehu
Àkọlé àwòrán, Ibi igbekun miran ni Katsina

Awọn Ọlọpaa ni Katsina tun ti ṣe abapade oriko ti wọn ti n muni sin yatọ si eyi ti wọn ti ri tẹlẹ.

Awọn ojuko yii lo maa n fara jọ bii ile iwe keu ṣugbọn to jẹ ibi ifiya jẹni ni pataki awọn ọmọ kekere.

Ile Iṣẹ Ọlọpaa ni Ipinlẹ Katsina sọ wi pe wọn so ọpọlọpọ awọn eniyan mọlẹ bii ẹran ti wọn si n fi iya jẹ wọn.

Ni Ọsẹ to kọja ni wọn ri ogunlọgọ awọn eniyan tu silẹ ni Ipinlẹ naa, ti iru iṣẹlẹ bẹẹ tun ti ṣẹlẹ bayii.

Ajọ Ọlọpaa naa ni ainiye agbalagba ati awọn ọmọ kekeeke ti ko din ni Ọgọrun ni wọn gba kale lati inu ile meji kan.

Awọn obi ni wọn n mu awọn ọmọ wọn lọ si ile iwe yii latari pe wọn yoo ni ẹkọ keu ati pe boya igbesi aye wọn yoo dara sii.

Ninu alaye ti ajọ Ọlọpaa ṣe fun ile iṣẹ BBC ni pe wọn maa n de awọn ọmọ naa mọlẹ ti wọn si tun maa n ba wọn lo pọ.

Wọn tẹsiwaju pe wọn kii fun wọn lounjẹ ti wọn si maa n fi iya to to iya jẹ wọn ninu ayika ti o dọti ti wọn ko wọn si.

Abẹnugan fun ile iṣẹ Olọpaa Ipinlẹ naa, Gambo Isa wi pe ni adugbo Marusa ni wọn ti ri ile ọhun.

Wọn ni iya ti wọn fi jẹ awọn ọmọ naa ko pọ to ti awọn ti ọwọ tẹ ni Daura.

Ọwọ awọn Olọpaa ko tii tẹ ẹni ti o jẹ adari ile naa ti o ti fẹsẹ fẹ. Wọn ni awọn si ti bẹrẹ si ni wa a bayii, ti Aarẹ Buhari si ti ni ki awọn Ọlọpaa bẹrẹ iwadii lori awọn iru ile bẹẹ.