Oyo Election Tribunal: Adelabu tún gbé Seyi Makinde lọ sí ilé ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn

Oríṣun àwòrán, OTHERS
Oloye Adebayo Adelabu ti ẹgbẹ oselu APC ti ni, oun ko faramọ idajọ ajọ eleto idibo to da igbẹjọ oun nu lori idibo to gbe Seyi Makinde wọle gẹgẹ bi gomina nipinlẹ Ọyọ.
Lẹyin ọjọ mọkanlelogun ti idajọ naa waye ni ilu Ibadan, ni Adelabu gbe ẹjọ lọ ile ẹjọ kotẹmilọrun.
Adelabu ati ẹgbẹ oselu APC sọ wi pe, magomago waye ninu idibo Ọjọ Kẹsan, Osu Kẹta, ọdun 2019, eleyii to gbe Seyi Makinde wọle gẹgẹ bi gomina.
- Fídíò rèé nípa bí Aláké tuntun ṣe ń gba ìwúre lábẹ́ Olúmọ kó tó gba adé
- Fasiti Eko ti "Cold Room" ni Staff Club wọn pa látàri ìwádìí BBC lórí àwọn olùkọ́ kan
- Ìṣesí Kunle Ọlasọpe ni mo ṣe yan iṣẹ́ akọ̀ròyìn láàyò - Lekan Alabi
- Sanusi Adebisi Idikan rèé, olówó tó ń san owó orí fún gbogbo ọkunrin ilẹ̀ Ibadan
Adelabu wa n beere lọwọ ile ẹjọ kotẹmilọrun lati sọ wi pe oun lo ni ibo to pọju lọ ninu idibo sipo gomina ni ipinlẹ Ọyọ abi ki wọn tun ibo naa di.
Ti a ko ba gbagbe, Alaga igbẹjọ naa, Justice Muhammed Sirajo salaye pe awọn da ẹjọ ti APC pe mọ Seyi Makinde nu nitori gbogbo awọn ẹlẹri ti Adelabu pe ko ni ẹri to daju, amọ ti wọn n sọ ahesọ lasan.








