Nedu Wazobia : Àyẹ̀wò DNA tí a ṣé fi hàn pé èmi kọ ní ìyàwó mí bí akọbi wà fún

Oríṣun àwòrán, NEDU&UZOR/IG
Lẹyin Gbas gbos to waye laarin akọrin takasufe Tuface Idibia ati iyawo rẹ lori aṣemaṣe ninu igbeyawo wọn, adẹrinposonu nii, Nedu Wazobia naa ti n fa surutu pẹlu iyawo rẹ tẹlẹ.
Ìyàwó Nedu lo kọkọ bọ sori ayelujara instagram rẹ lati ṣalaye nnkan ti oju rẹ ri ninu igbeyawo rẹ pẹlu Ani Chinedu Emmanuel ti gbogbo eniyan mọ si Nedu
Ohun taa gbọ ni pe iyawo rẹ tẹlẹ Uzoamaka Ohiri niṣe ni Nedu maa n lu oun ni ilukulu ti o si fi foto awọn apa to wa ni ara rẹ han.
Nedu ti orukọ rẹ n jẹ Ani Chinedu Emmanuel ati iyawo rẹ tẹlẹ Uzoamaka Ohiri lawọn eeyan tun mu ọrọ wọn bẹnu bayi lori ayelujara ni Naijiria.
Ninu awọn ẹsun to fi kan Nedu, Uzoamaka sọ pe lẹyin ọsẹ diẹ ti oun ṣiṣẹ abẹ bimọ fun Nedu, ''Alhaji Musa'' lu oun lalubami lójú iya rẹ to gbe ọmọ tuntun ti oun bi lọwọ
Koda o fi awọn aworan ṣọwọ loju opo Instagram lati ṣafihan oju apa ibi ti o sọ pe Nedu ti lu oun.
Gbogbo ẹsun ti o fi kan wọnyi, Nedu sọ pe ko si ootọ ninu rẹ.

Oríṣun àwòrán, Instagram/nedu_wazobiafm
Ninu esi rẹ, o ni bi eeyan kankan ba tiẹ fẹ sọ ọrọ nipa ifiyajẹni ninu igbeyawo awọn, oun loun yẹ ko fẹsun kan an iyawo rẹ tẹlẹ.
O ni awọn ọlọpaa tiẹ ti ṣe iwadii ọrọ naa nigba tawọn fẹ mu opin ba ajọṣepọ wọn.
''Lori ẹsun pe mo fiya jẹ ninu igbeyawo wa, awọn ọlọpaa ti wadii ọrọ yi lẹẹmeeji , akọkọ ni agọ ọlọpaa Ajah ati igbakeji ti ile ẹjọ ṣe iwadii ọrọ yi ki wọn to tu igbeyawo wa ka''

Oríṣun àwòrán, Instagram/nedu_wazobiafm
Ni igba mejeeji, wọn ni mi o jẹbi ẹsun wọn yi mo si ni iwe ẹri lati fi gbe ọrọ mi lẹyin.
Ko tan sibẹ, Nedu sọ pe oun gbe awọn ọmọ mẹta tawọn bi lọ fun ayẹwo DNA ti esi si fi han pe akọbi ọmọ awọn kii ṣe ọmọ oun.

Oríṣun àwòrán, Instagram/nedu_wazobiafm
''Ọpọlọpọ ipenija lo koju igbeyawo wa. Lara rẹ ni agbere ti iyawo mii n ṣe eyi to mu ki n lọ ṣe ayẹwo fun wọn ti esi si fi han pe akọbi wa kii ṣe ọmọ mi botilẹ jẹ wi pe a jijọ n gbe pọ bi lọkọlaya.''
















