Super Falcons 2022: Kílódé tí wọ́n ti ìlẹ̀kùn mọ́ Super Falcons ni pápákọ̀ òfurufú l'Abuja?

Awọn agbabọọlu Super Falcons Naijiria

Oríṣun àwòrán, Credit/Nigeria Super Falcons/Instagram

Ẹgbẹ agbabọọlu obinrin fun Orile-ede Naijiria, Super Falcons pada si Naijiria ni Ọjọbọ

Eyi waye lẹyin ti wọn lu ẹgbẹ agbabọọlu Ivory Coast pẹlu ami ayo mẹta sodo lati pegede fun idije ere bọọlu awọn obinrin nilẹ Afirika, AWCON.

Ṣugbọn oju wọn ri to nigba ti baalu to gbe wọn pada si Naijiria balẹ ní papakọ ofurufu ilu Abuja.

Fidio kan to lu ayelujara pa ṣàfihàn bi wọn ko ṣe ri ọna kọja kuro ni papakọ ofurufu naa.

Wakati melo ni won fi da awon agbabọólu wa duro?

Iroyin sọ pe wakati mẹta ni wọn fi wa ni papakọ ofurufu naa lai raye jade.

Agbabọọlu kan lara wọn, Uchenna Kalu tiẹ sun silẹ ninu irora to sí dabi ẹni pe o ni k'awọn oṣiṣẹ eleto tọju rẹ.

Awọn agbabọọlu n fi ibinu sọrọ ninu fidio ọhún lori ohun ti oju wọn ri papakọ ofurufu.

Ohun ti a gbọ pe o ṣẹlẹ ni pe eto lori ilana covid 19 lo fa idaduro naa fun ni papakọ ofurufu Abuja.

Àkọlé fídíò, Diabetes Ulcer

-Ajọ FAAN sọrọ lori idaduro Super Falcons ni papakọ ofurufu Abuja

Oludari ajọ FAAN to n ri si ọrọ papakọ ofurufu ni Naijiria, Henrietta Yakubu, ajọ NCDC to n gbogun ti ajakalẹ arun ati ajọ eleto abo, AVSEC lo dena mọ Super Falcons lẹyin ti wọn tako ilana ati dẹkun covid 19.

Arabinrin Yakubu ni ẹgbẹ agbabọọlu Super Falcons kọ lati san owo to yẹ ki wọn san fun NCDC lori ọrọ coronavirus nigba ti wọn de sí Abuja lati Ivory Coast.

O ṣalaye pe awọn agbabọọlu naa ni wọn fẹ gb'owo ẹyin lọwọ awọn ni.

Àkọlé fídíò, Akàwégboyè alákàrà

Kini Minista tun sọ?

Yakubu ni "awọn mii rin lọ si ibi to wu wọn, ṣugbọn wọn ni lati pada wa san owo naa lẹyin ti ilẹkun wa ni titi.

Àkọlé fídíò, Bukola Odufuwa: Mo ń ta oúnjẹ fáwọn akẹ́kọ̀ọ́, gbálẹ̀, fọ aṣọ, pọnmi láì tọrọ agbe jẹun

Ẹwẹ, minisita ere idaraya, Sunday Dare ati aarẹ ajọ elere bọọlu NFF, Amaju Pinnick ti bu ẹnu atẹ lu iṣẹlẹ naa.

Ajọ NFF ni ohun gbogbo to yẹ ki Super Falcons ṣe ní wọn ṣe nigba ti wọn de si papakọ ofurufu ilu Abuja.

Minisita ti wa sọ pe ajọ NCDC ni lati ṣe iwadii iṣẹlẹ naa ni kiakia.