BBC Gov Debates: Ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé níbi ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá l'Ọyọ

ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá
Àkọlé àwòrán, ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá

Ni kete ti oju opo facebook BBC News Yoruba ti ṣi silẹ fun akanṣe Facebook Live ipade ifọrọwerọ awọn oludije gomina ipinlẹ Ọyọ ni oniruuru eto ti a le gbadun ti bẹrẹ.

Lakọkọ, lati ibẹrẹ ni ara ọtọ eyi ti BBC Yoruba ṣe - fifi ọrọ wa awọn akopa lẹnu wo nibi iforukọ silẹ lori ki ni wọn wa ṣe ati ireti wọn latọdọ awọn oludije ti yoo kopa nibi eto naa.

Awọn akopa ko figba kan bọkan ninu idahun wọn si BBC Yoruba nitori wọn nifẹ lati mọ ẹni to ni alakalẹ gidi fun awọn araalu.

Àkọlé fídíò, BBC Gov Debates: Ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ni àwọn olùdíje yóò ṣe
ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá
Àkọlé àwòrán, ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá

Bakan naa ṣaaju eto ni wọn wọ inu ibi igbalejo ti gbogbo awọn oludije naa wa ki eto to bẹrẹ lati bere iwoye wọn nipa ipade ifọrọwerọ yii paapaa ti yoo ko atọrẹ ati alatako pọ soju kan naa leyii to jẹ wi pe loriṣiriṣi ọna ni wọn ti fi ọ̀rọ̀ ati iṣe ta ko ara wọn tẹlẹ nitori idibo.

ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá
Àkọlé àwòrán, ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá

Fun apẹrẹ, lasiko yii, oludije fun ẹgbẹ oṣelu APC, Adebayo Adelabu ni kò ṣe oun lara bakan bakan pe gbogbo awọn kọkọ jọ wa ninu yara kan naa tori baba, ẹgbọn ati ọrẹ ni awọn toku jẹ si oun.

Àkọlé fídíò, Ademọla Ogunbanjo: A nílò bàbá ìsàlẹ̀ nínú òsèlú

Sẹnetọ Olufẹmi Lanlẹhin ti ẹgbẹ oṣelu ADC ṣalaye pe ireti oun nibi eto yii ni ki ijọba tiwa n tiwa ko lọ deede lai si aawọ tabi ija. Olufẹmi Lanlẹhin kan sara si ile iṣ BBC fun agbekalẹ eto. O ni ọm ipinlẹ Ọyọ ni gbogbo awọn oludije ti awọn jọ joko, ẹgbọn ati aburo si ni gbogbo awọn.

ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá
Àkọlé àwòrán, ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá

Ni ti Ọtunba Alao Akala, o gboriyin fun BBC fun akitiyan yii lati gbe ede ati aṣa Yoruba larugẹ. O ni ko sohun to tuntun ninu pe awọn jọ joko sinu ibi kan tori gbogbo awọn lawọn m ara awn ti ko si si ija kankan laarin wọn.

Àkọlé fídíò, Falana: Awọn to n dije dupo ìdìbò 2019 fẹ́ fa ogun si Naijiria

Lasiko ipade itagbangba nigba ti ifọrọwerọ naa bẹrẹ, awọn ọrọ kanka kanka n jẹ jade ninu awọn ọrọ ti awọn oludije sọ ti ọpọlọpọ ko si ni gbagbe.

Alao Akala ti ẹgbẹ oṣelu ADC juwe ara rẹ gẹgẹ bi aloku ọlọpaa. "Aloku Ọlọ́pàá ni mí nítorínáà mo mọ̀ nípa àbò dáadáa".

ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá l'Ọyọ
Àkọlé àwòrán, ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá l'Ọyọ

Bakan naa, oun lo ni "àtàrí àjànàkú ni ọ̀rọ̀ ìpínlẹ̀ Ọyọ ..., ọ̀rọ̀ ìpínlẹ̀ Ọyọ àtàrí àjànàkú ni, àgbàlagbà bíi tèmi ló nílò".

Oun lo kọkọ sọ wi pe iṣejọba oun yoo san N30,000 owo oṣu ti àwọn òṣìṣẹ́ n ja fun. O ni "owó ti pọ̀ nísisìyìí ju ìgbà tí mo kọ́kọ́ wà nípò lọ". Lẹyin naa ni atọkun bere ọrọ N30,000 yii lọwọ awọn to ku ti gbogbo wọn si ni awọn yoo san awọn.

Ọmọbọlanle Sarumi-Aliyu ko kẹrẹ rara pẹlu awọn ọrọ rẹ lati ibẹrẹ titi de opin to bẹẹ to fi jẹ wi pe bi awn kan ṣe n kan sara sii ni awn mii ni idakeji n bu ẹnu atẹ lu bi o ṣe sọrọ.

ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá l'Ọyọ
Àkọlé àwòrán, ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá l'Ọyọ
ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá l'Ọyọ
Àkọlé àwòrán, ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá l'Ọyọ

Nipa eto ẹkọ o ni "wọn kò fẹ́ kọ́mọ́ mẹ́kúnù di Dókítà" nitori naa oun yoo mojuto eto ẹkọ. O tun fa oju awọn ọdọ ilu gan mọra, o ni "mo fẹ́ sọ àwọn Area Boys di ọmọ mi" o ni ki awọn ọdọ ma jẹ ki oloṣelu kankan lo wọn nilokulo mọ ti "wọn ko si fun un yin niṣẹ tabi ki ẹ tilẹ̀ le fẹ ọmọ wọn ṣugbọn tọrọ kọbọ ni wọn fi n gun yin lọwọ bi ẹ ba ti dibo tan wọn a tun rọọ yin sẹyin". Fun eyi, awọn eniyan roo latẹwọ waa waa.

ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá
Àkọlé àwòrán, ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá

O ni "bí Ọyọ bá dán obìnrin wò, Ọyọ a dùn ún wò, kò ní sí ọ́fíìsì ọkọ gómìnà" nitori naa, oun yoo ṣe owo ilu ti wọn ko ki n lo daadaa tẹlẹ daadaa bayii.

Sarumi ni "maa gba Lautech pada, maa fun ijọba ibilẹ lagbara wọn pada.

ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá
Àkọlé àwòrán, ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá

Fun Sẹnetọ Olufẹmi Lanlẹyin, eniyan kan fi ibeere ranṣẹ wi pe baba isalẹ kan lo n pọn ọn sẹyin kiri pe bi o ba di gomina tan ṣe ko ni maa fi ti baba isalẹ yii ṣe akọkọ ninu ohun gbogbo.

O dahun pe oun ko m nipa baba isal ti wọn n sọ. O si ni ṣugbọn ọmọde gbọn agba gbọn la fi da Ile Ifẹ. Awọn ko yọ ẹnikẹni sil ninu ẹgb oṣelu oun. Pataki julọ, o ni orukọ rere ti oun ti ni lati igba ti oun ti ṣe Sẹnetọ ko ni bajẹ.

O ni "A o tun ile iwe awọn akanda ṣe, ọrẹ araalu ni Senator Lanlẹhin nitori naa a o ni yan ọrẹ ati ojulumọ sipo afi ara ilu. Ijọba tiyin lo maa jẹ. Baba to bi mi ṣe aṣeyọri emi naa yoo si ṣe e".

ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá
Àkọlé àwòrán, ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá

Adebayo Adelabu ti ẹgbẹ oṣelu APC ni wn bi pe bawo lo ṣe fẹ ṣee lai ni iriri kankan ri to fi fẹ bẹrẹ pẹlu jijẹ gomina. O fesi pe "inú mi dùn pé mi o ní ìrírí nínú òṣèlú nítori òṣèlú Nàìjíríà kò ṣe é mú yangàn," o ni ọna ati ṣejọba gangan lo yẹ kii ṣe ka fi oṣelu wọle ka tun tẹsiwaju ninu oṣelu ti a ba de ipo. O ni ọna atiṣejọba ni wn fi kọ oun lẹkọọ kii ṣe ka kan maa ṣe oṣelu.

O ni gẹgẹ bi ẹni to ti ṣe igbakeji gomina banki ile ifowopamọ to ga ju ri nitori naa ati ṣe gomina ko le nira.

O lodi si oun ti Oloye Alao Akala sọ pe atari ajanaku ni ọrọ ipinl Ọyọ.

Fọfọ ni gbọngan ibi ipade kun fun ero latoke de isalẹ gẹgẹ bi awọn ara ipinlẹ Ọyọ ṣe wa lati kaakiri ki wọn lee mọ nipa aato awọn oludije.

ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá l'Ọyọ
Àkọlé àwòrán, ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá l'Ọyọ