Ọ̀nà tí àwọn olùdíje ipò gómínà ní Ìpínlẹ̀ Ọyọ fẹ̀ gbà yànjú ọ̀rọ̀ ààbò rèé
Ero awọn oludije mẹrin fun ipo gomina Ipinlẹ Oyo ṣe ọtọtọ, ṣugbọn gbogbo wọn lo ṣe ileri lati yanju ọrọ aabo.
Awọn mẹrin to kopa ninu ipade itagbangba BBC News Yoruba to waye ni Ibadan ni ọjọ Ẹti, ọjọ Kinni, Osu Keji ni Oloye Adebayo Alao-Akala (ADP), Adebayo Adelabu (APC), Sẹnetọ Olufemi Lanlehin (ADC) ati Ọmọọba Bolanle Sarumi-Aliyu (NIP).
Oludije fun ẹgbẹ oṣelu NIP Ọmọọba Bolanle Sarumi-Aliyu beere ibeere kan lọwọ àwọn ọdọ, eyi to fa ki aruwo sọ ninu gbọngan naa. O ni, "Ẹyin ọdọ ti awọn oloṣelu n lo fun jagidijagan, to ba jẹ bẹẹ ni wọn fẹran yin to, ẹ ṣe wọ inu ile wọn ki ẹ lọ ba wọn jẹun tabi ki wọn tilẹ jẹ ki ẹ fẹ awọn ọmọ wọn?"