BBC Gov Debates: Èyí ni bí àwọn olùdíje sípò gómìnà Ọyọ ṣe fẹ́ ẹ̀ tún ètò ẹ̀kọ́ ṣe

Àkọlé fídíò, BBC Gov Debates: Ètò ẹ̀kọ́ ọ̀fẹ́ ni àwọn olùdíje yóò ṣe

Nibi ipade ijiroro ti BBC Yoruba ṣe pẹlu awọn oludije fun ipo gomina atawọn oludibo nipinlẹ Ọyọ, ara ọrọ to jẹyọ ni erongba ti ẹni kọọkan awọn oludije ni fun eto ẹkọ.

Bakan naa ni ọrọ Fasiti Ladoke Akintọla (LAUTECH) to wa ni ilu Ogbomọṣọ naa jẹyọ. Ọpọ igba si ni ileewe naa maa n wa ni titi pa nitori iyanṣẹlodi awọn oṣiṣẹ ibẹ.

Adebayọ Adelabu ni oun yoo ri i daju pe ipinlẹ Ọyọ gba Fasiti LAUTECH pada.

Bakan naa ni Alao akala sọ pe oun yoo gba LAUTECH lọwọ ipinlẹ Ọṣun laarin ọgọrun ọjọ t'oun ba de ipo.

Fun Olufẹmi Lanlẹyin, sọ pe ọrọ LAUTECH jẹ oun logun, maa san owo awọn olukọ deede.

Ọmọọbabinrin Bọlanle Sarumi-Aliyu ni ti ẹ sọ pe ''maa gba LAUTECH pada, maa si kọ fasiti mii silu Ibadan.''

Ṣugbọn ohun to wọpọ ninu idahun awọn oludije naa ni pe awọn yoo ṣe eto ẹkọ ọfẹ fun awọn akẹkọọ ileewe alakọbẹrẹ ati girama to wa ni ipinlẹ Ọyọ.