BBC Gov Debate: ìpàdé ìfọ̀rọ̀wérọ̀ BBC Yorùbá
Keku ile o gbọ ko sọ fun toko lọrọ ipade ifọrọwerọ BBc Yoruba nipinlẹ Ọyọ ku bayii.
Nitori gbogbo eto to yẹ ni tito lati ọwọ ile iṣẹ igbohunsafẹfẹ BBC Yoruba lo ti to fun ipade ifọrọwerọ ti yoo waye laarin awọn oludije fun ipo gomina ni ipiinlẹ Ọyọ.
Gbọngan Professor Ogunlesi ni yoo ti waye ni fasiti ilu Ibadan.
Awọn akopa yoo bẹrẹ si ni fi orukọ silẹ ṣaaju ki eto naa to bẹrẹ ni nkan bii agogo mẹsan owurọ.
Bẹẹ si ni awọn ara ipinlẹ Ọyọ ati awọn ololufẹ bi idibo ipinlẹ Ọyọ yoo ṣe ri ti n foju sọna de awọn gomina ti wọn yan pe awọn fẹ ri nibi ipade ifọrọwerọ naa.