Nigeria Elections 2019: Bàbá rẹ̀ àgbà ni Adegoke Adelabu Pẹnkẹlẹmẹ́sì

Oríṣun àwòrán, Adebayo_adelabu
Agbo ile Oke Oluokun ni adugbo Kudẹti nilu Ibadan ni wọn ti bi Adebayọ Adelabu lọjọ kejidinlọgbọn osu Kẹsan ọdun 1970.
Aderibigbe Adelabu ni orukọ baba rẹ, ti baba rẹ agba, Adegoke Adelabu, ti gbogbo eeyan mọ si ‘Pẹnkẹlẹmẹsi’ nigba aye rẹ, si jẹ gbaju-gbaja agba oselu nilẹ Ibadan.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Awọn ile-ẹkọ ti Adebayọ Adelabu lọ
Adebayọ lọ si ileẹkọ alakọbẹrẹ Ibadan Municipal Government (IMG), to wa ni adugbo Agodi nilu Ibadan, laarin ọdun 1976 si 1982, ko to morile ile ẹkọ girama Lagelu Grammar School lọdun 1982 nibi to ti jade iwe mẹwa lọdun 1987.
Adebayọ gba oye imọ ijinlẹ akọkọ, Isọri kinni (First Class) ninu imọ nipa isiro owo (Accountancy), nile ẹkọ fasiti Ọbafẹmi Awolọwọ nilu Ile Ifẹ, to si jẹ ọmọ ẹgbẹ awọn akọsẹmọsẹ oluṣiro owo lorilẹede Naijiria, ICAN.

Oríṣun àwòrán, Adebayo_Adelabu
Awọn ileeṣẹ ti Adebayọ Adelabu ti ṣisẹ bii oluṣiro owo
Ileeṣẹ oluṣiro owo kan to jẹ tilẹ okeere amọ ti ẹka rẹ fidi kalẹ si orilẹede Naijiria, ti wọn pe ni PriceWaterhouseCoopers ni Adebayọ ti kọkọ ṣisẹ ni kete to jade nile ẹkọ fasiti.
Ọdun meje gbako lo lo nile isẹ naa, to si dari oniruuru ẹka lab ileesẹ ọhun nilẹ yii ati loke okun.
Lọdun 1999 lo gba aye lati lọ ṣare sisẹ pẹlu banki apapọ ilẹ wa (CBN), fun ọdun kan pere, nibẹ lo si ti ko ikọ kan sodi eyi to ṣe atunto banki agba naa, eyi ti wọn pe akori rẹ ni akanse isẹ ‘Project Eagles’.

Oríṣun àwòrán, @BayoAdelabu
Ọdun 2009 lo fi ileesẹ PriceWater silẹ gẹgẹ bii Alakoso eto ayẹwo iwe owo, to si lọ dara pọ mọ banki olokoowo First Atlantic.
Lẹyin eyi lo tun lọ ṣiṣẹ ni Standard Chartered Bank, to si di ipo Oludari fun ẹka isuna ati aato banki naa fun ẹkun iwọ oorun Afrika mu, ti ọọfisi rẹ si wa nilu Eko ati Abuja.
Banki yii lo wa titi to fi di Oludari agba fun First Bank of Nigeria lọdun 2009, ẹni ọdun mọkandinlọgbọn si ni nigba to de ipo giga ọhun.

Oríṣun àwòrán, @Adebayo_Adelabu
Aarẹ ana, Goodluck Jonathan lo yan Adebayọ bii igbakeji Gomina fun banki agba ilẹ wa loṣu keji ọdun 2014, ipo yii si lo wa to fi fẹyin ti.
Irinajo oṣelu Adebayọ Adelabu
Yatọ si pe gbaju-gbaja olokoowo ni Adebayọ, to si ni ileesẹ aje kaakiri ilu Ibadan, o tun jẹ eekan ti ko ṣe fi ọwọ rọ sẹyin lagbo oṣelu nipinlẹ Ọyọ.
Ogunjọ oṣu Kẹfa ọdun 2018 lo si yọju sita bii oloselu lasiko to fi erongba rẹ han nileesẹ gbe oṣelu APC lati dije ninu ibo abẹle ẹgbẹ naa fun ipo gomina ipinlẹ Ọyọ.

Oríṣun àwòrán, @BayoAdelabu
Adebayọ lo jawe olubori ninu ibo abẹnu ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọyọ ninu ibo abẹnu to waye lọgbọjọ oṣu Kẹsan-an ọdun 2018 gẹgẹ bii oludije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu naa.














