Nigeria Independence Day: Sé ẹ mọ̀ pé ọdún 1956 ló yẹ́ ká ti dòmìnira ṣùgbọ́n....
Awọn Oba ilẹ̀ Yoruba n gba owo ẹyin lọwọ awọn oloṣelu - Adebanjọ
Bi ọmọde ba ṣubu, a wo iwaju; bi agba ba ṣubu, a wo ẹyin wo, ọrọ Naijiria gba apero ọmọ eriwo lasiko yii ti a n ṣe ayajọ ọdun ominira.
Oni ni Naijiria pe ẹni ọdun mọkandinlaadọta lẹyin ti a gba ominira kuro lọwọ ijọba amunisin ilẹ Gẹẹsi lọjọ kinni, oṣu kẹwaa, ọdun 1960.
Oloye Ayo Adebanjo to jẹ adari ẹgbẹ awọn ọmọ Yoruba ti gbogbo aye mọ si Afẹnifẹre ṣalaye lori bi Naijiria ṣe gba ominira ati awọn akọni to jija ẹ Ǹ jẹ́ o mọ àwọn èèyaǹ wọ̀nyí tó jà fún òmìnira Nàìjíríà?.
Adebanjo ṣalaye ipa pataki ti Awolowo Obafemi, adari ijọba iwọ oorun guusu Naijiria atijọ ko lati paṣẹ\eto ẹkọ ọfẹ kanpa fun gbogbo ọmọde nilẹ Yoruba.
Olori Afẹnifẹre sọ itan ṣaaju ominira ati ohun ti Awolowọ, Saudana ati Azikiwe ṣe pe o too royin.
O sọrọ nipa ijẹkujẹ awọn aṣaaju Naijiria lasiko yii bẹrẹ lati ori Aṣiwaju Tinubu ati awọn lọbalọba ni eyi to ni ko mu itẹsiwaju ba iran Yoruba mọ.