BBNaija: Diane ń domi lójú bí ẹni ọ̀fọ̀ ṣẹ̀ nígbà tí ilé ẹlẹ́gbọ́n àgbà taare ìpàkọ́ rẹ̀ sílé

Diane

Oríṣun àwòrán, @BBNaija

Àkọlé àwòrán, Awọn ololufẹ rẹ ti n fi eroungba wọn lede bayii lori ẹrọ ayelujara

Wọn ti yọ Diane kuro ninu idije ẹlẹgbọn agba Big Brother to n lọ lọwọ.

Wọn sọ fun Diane pe ko kẹru rẹ kuro ni ile ẹlẹgbọn naa lẹyin ti Frod mu owo kan ti orukọ rẹ wa lara rẹ.

Ni ṣe ni Diane n domi loju bi ẹni ọfọ ṣe lẹyin ti wọn le kuro ninu ile ẹlẹgbọn agba naa, ti Omashola si n fo fayọ nigba ti ori ko yọ.

Ṣaaju ni Big Brother ti kede loju opo Twitter rẹ pe ẹnikan yoo pada sile lalẹ oni laarin Diane ati Omashola.

Lẹyin ti wọn ti ni ki Diane pada sile bayi ni awọn ololufẹ rẹ ti n fi eroungba wọn han lori ẹrọ ayelujara.

Bẹẹ ni awọn miran si ki Omashola ku ori ire pe o si wa nini ile ẹlẹgbọn naa.

Àkọlé fídíò, Intersextuality: Dokita ni ká mu èyì tó wù wá nínú jíjẹ́ akọ tàbí abo