Intersex: Dokita ni ká mu èyì tó wù wá nínú jíjẹ́ akọ tàbí abo

Àkọlé fídíò, Intersextuality: Dokita ni ká mu èyì tó wù wá nínú jíjẹ́ akọ tàbí abo

Awọn eeyan a maa na mi, ge irun mi, wo mi pẹlu oju ti ko dara; bẹẹ kii ṣe ẹ̀bi mi - Mystique

Kini o kọkọ wa si ọkan rẹ bi o ṣe gbọ apejuwe ẹni kan to ni nkan ọmọkunrin ati tọmọbinrin papọ?

Iroyin yii da lori àwọn ọmọ Naijiria meji ti wọn ni lati yan boya wọn fẹ jẹ akọ tabi boya wọn fẹ jẹ abo.

James Johnson ati Mystique Evolving ni Aṣẹda da pẹlu nkan ọmọkunrin ati tọmọbinrin papọ lọjọ ti a bi wọn.

Ọkan ninu awọn ikoko ẹgbẹrun meji ti a bi ni wọn n ni nkan ọmọkunrin papọ mọ ti ọmọbinrin.

Igba miran kete ti abi iru wọn lo ti maa n han ni eyi ti kii han ni ọjọ ibi fun awọn miran titi wọn a fi dagba diẹ.

Ko si akọsilẹ pe awọn ti wọn ni nkan ọmọkunrin ati nkan ọmọbinrin papọ wa ni Naijiria ṣugbọn eyi ko sọ pe ko si iru wọn.

BBC Oyinye, Harry ati Samuel ṣalabapade awọn meji pẹlu ifọrọwanilẹnuwo to kun.

Wọn ṣalaye kikun lori ipenija to n kopju awọn mejeeji ni Naijiria lataari bi Adẹdaa ṣe ṣeda wọn.

James Johnson:

A bi James Johnson pẹlu nkan ọmọkunrin ati nkan ọmọbinrin papọ ṣugbọn awọn obi rẹ gba pe obinrin ni ọmọ wọn.

Wọn sọ orukọ rẹ ni Iyabọ Abade.

Odun 1997 si 1998 ni Iyabọ to mọ pe oun yatọ sawọn eniyan to ku.

Nigba ti o nṣoju Naijiria gẹgẹ bi agbabọọlu obinrin ninu idije AFCON ati FIFA ni o ṣẹṣẹ hande sita.

Iyabo

Oríṣun àwòrán, @iyabo

Àkọlé àwòrán, Iyabo kuro ninu egbe agbboolu obinrin Naijiria lasiko ipagọọ wọn nigb ato ri aduru iyatọ ounn atawọn akẹgbẹ rẹ.

Lẹyin to pe ọmọ ọdun mọkandinlogun gẹgẹ bii obinrin ni wọn ṣẹṣẹ lọ ṣe iṣẹ abi fun un.

Wọn rii pe o jẹ akọ ni ida adọrin ati abo ni ida ọgbọn ninu ọgọrun un.

O yan lati di ọkunrin, o si di James Johnson lẹyin iṣẹ abẹ rẹ.

Mystique Evolving:

Kete ti a bi Mystique ni a ri nkan ọmọkunri rẹ ni eyi ti wọn fi gba pe ọmọ okunrin ni.

Bi o ṣe n dagba lo n jọ obinrin sii ninu ohùn ati oju rẹ.

obinrin

Oríṣun àwòrán, @Mystique

Àkọlé àwòrán, Leyin to pari ile iwe girama ni won n buu pe o n se ako si ako

Nigba to ya Mystique gun ọyan bi obinrin, ikun maa n dun un bi ẹni to n ṣe nkan oṣu lẹẹkan loṣu.

Nile iwosan ni iwadii ti fihan pe o nile apo ẹyin obinrin ṣugbọn ko ni ile ọmọ.

James

Oríṣun àwòrán, @James

Àkọlé àwòrán, James ni oun ti gbagbe gbogbo nkan ti oun fi n je Iyabo

Awọn Ipenija to n koju àwọn mejeeji:

Didẹyẹsi ni olori iṣoro to n koju awọn to ni ǹkan ọmọkùnrin àti ti ọmọbìnrin papọ.

Awọn eniyan Naijiria ko ni oye kikun ohun to n je ki eniyan ni ǹkan ọmọkùnrin àti ti ọmọbìnrin.

Opọ gba pe ajẹ, emere ati ẹni bi to yẹ ki wọn sọ okuta pa ni wọn jẹ.

Mystique ni o le ni ọdun mẹwaa ti awọn ẹbi fi n sa fun oun yatọ si ẹgbọn rẹ kan.

Mystique

Oríṣun àwòrán, @mystique

Àkọlé àwòrán, Opo ko mọ pe agba kadara ni

Lẹyin ti James kuro nibi idije AFCON lọdun 1999 lo gba California lọ ni Amerika fun iṣẹ abẹ to sọọ di ọkunrin pẹlu iranlọwọ awọn aṣojuṣofin.

Lọdun 2005 lo pada wa si Naijiria wa gba bọọlu fun awọn ọdọ ti ko tii pe ogun ọdun.