Manchester United vs Arsenal: Ta ni yóò borí nínú ìjà arọ méjì yìí?

Oríṣun àwòrán, Twitter/Premier League
Ẹgbẹ agbabọọlu meji ti muṣemuṣe wọn ko da muṣemuṣe to, Manchester United ati Arsenal lo fẹ koju ara wọn lalẹ ọjọ Aje ni papa iṣere Old Trafford ninu idije English Premier League.
Awọn ẹgbẹ agbabọọlu mejeeji ni wọn kọ lati ṣe iwuri fawọn ololufẹ lati igba ti saa bọọlu tuntun yii ti bẹrẹ.
This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.
End of X post
Ikọ Man U ni tiẹ ti fidi rẹmi nigba meji, bẹẹ ni wọn ta ọmi lẹẹmeji ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹfa ti wọn gba ninu idije EPL ti saa yii.
Ifẹsẹwọnsẹ meji pere ni Manchester UNited ti jawe olubori ninu ere bọọlu mẹfa ti wọn kopa ninu rẹ.
Arsenal tun gbe pẹẹli diẹ ni ti wọn nitori ipo kẹjọ lawọn wa nigba ti Man U wa ni ipo kọkanla lori tabili idije EPL.
Ninu ifẹsẹwọnsẹ mẹta ni Arsenal ti fakọyọ ninu meje ti wọn ti gba ni saa bọọlu yii.
Arsenal fidi rẹmi ninu ifẹsẹwọnsẹ kan, bẹẹ ni ni wọn ta ọmi ninu ere bọọlu meji.








