FBI: À ń ṣe ìlanilọ́yẹ f'awọn abo lórí ìtọ́jú àrùn jẹjẹrẹ
Mosinmiloluwa Tenabe ni ó ń darí ẹgbẹ́ FBI tó ń ṣe ìpolongo lórí àrùn jẹjẹrẹ ọyàn àti ǹkan ọmọbìnrin yìí

Ẹgbe yii ni FBI, tó túmọ̀ si Female Bikers Initiative, ti wọn gbe kalẹ fún ṣiṣe ìpolongo fún àwọn obìnrin lórí àyẹ̀wò àti ìtọ́jú àrùn jẹjẹrẹ ọyàn àti ǹkan ọmọbìnrin.
Tenabe sọ̀rọ̀ lórí bi wọ́n ṣe ń kó owó jọ lati ọ̀dọ̀ àwọn alátìlẹyìn wọn ti wọn ti fi ṣe àyẹ̀wò ọyàn àti ǹkan ọmọbìnrin fún ẹẹdẹgbẹta obinrin lọdun to kọja.
O mẹnuba ìpinnu ẹgbẹ naa fún tọdun yii lati ṣeto àyẹwo fún ẹgbẹrun marun un obìnrin ni 2018

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
Ẹgbẹ FBI yii ṣe àwọn iwe ìléwọ́ keekeeke ti wọ́n ń pín fún àwọn obìnrin ki wọn fi le mọ ibi ti wón le lọ fún àyẹ̀wò àti itọju lórí àrùn jẹjẹrẹ ọyàn àti abẹ́.
Tenabe ni o tó ọdun mẹsan an ti òun ti n wa alupupu òun.









