Moroccan Journalist: Hajar Raissouni de èrò ẹwọn lórí ẹ̀sùn àgbèrè àti oyún ṣíṣẹ́

Oríṣun àwòrán, Reuters
Akọroyin ọmọ orile-ede Morocco kan ti fẹwọn ọdun kan gbara lori ẹsun pe o ni ibalopo ṣaaju ki o to lọkọ ati pe o ṣẹyun.
Awọn ajafẹtọẹni ni ẹjọ rẹ ti tan imọlẹ si ilakaka ijọba lati dẹgun le awọn akọroyin to n bẹnu atẹ lu u Wọ́n gbé Akọ̀ròyìn ní Morocco lọ sílé ẹjọ́ lórí ẹ̀sùn àgbèrè àti oyún ṣíṣẹ́.
Niṣe ni awọn agbofinro mu Hajar Raissouni ati afẹsọna rẹ nigba ti wọn jade lati ile iwosan awọn alaboyun kan ni ilu Rabat loṣu Kẹjọ.
Ọmọ ọdun mejidinlọgbọn naa tako ẹsun ti wọn fi kan an, ti o si ṣalaye pe niṣe ni oun gba itọju fun bi ẹjẹ ti ṣe n ya lara oun.
Arabinrin Raissouni n ba ile iṣẹ iroyin aladani kan ṣiṣẹ eleyi ti o saaba ma n bẹnu ẹtẹ lu awọn alaṣẹ.
O ni ijọba n dun kooko mọ oun ni ati pe wọn ti ṣaaju bere nipa iṣẹ ati mọlẹbi oun ki wọn to gbe oun.
Iboju dudu ni Hajar Raissouni wọ wa si ile ẹjọ ni Rabat, to jẹ olu ilu Morocco. Oun ati afẹsọna rẹ ti o jẹ ọmọ orile-ede Sudan sọ pe awọn ko ṣẹyun.
Agbẹjọro rẹ Abdelmoula El Marouri sọ pe: ''iyalẹnu ni idajọ yi jẹ fun wa'' ti o si sọ pe niṣe lo yẹ ki wọn tu u silẹ pẹlu gbogbo ẹri ti awọn gbe wa siwaju ile ẹjọ.
O ni awọn yoo tako idajọ naa.
Hajar ni akọroyin to n ṣiṣẹ pẹlu ileeṣẹ iwe iroyin Akhbar Al-Yaoum.
Agbẹjọro ijọba ni bi wọn ti ṣe mu akọroyin naa ko ni ohun kankan ṣe pẹlu pe o jakọroyin ati pe ile iwosan aboyun to lọ lawọn agbofinro ti n ṣọ ọ tẹlẹ nitori pe wọn fura si pe awọn eeyan n ṣe oyun nibẹ lọna to tako ofin.
Ile ẹjọ dajọ ẹwọn ọdun kan fun afẹsọna rẹ ti dokita to wa nile iwosan naa si fẹwọn ọdun meji jura.
Awọn to n ba dokita naa ṣiṣẹ ati nọọsi to wa nibẹ naa ko lọ lai jiya.
Ahmẹd Benchemsi, oludari ajọ to n ja fẹtọ ọmọniyan lagbegbe naa ṣapejuwe idajọ yi gẹgẹ bi ''ọjọ buruku'' forile-ede Morocco.













