China - Rògbòdìyàn bẹ sílẹ lọjọ òmìnira àádọ́rin ọdún ilẹ China

Awọn Olọpaa ilẹ China
Àkọlé àwòrán, China - Rògbòdìyàn bẹ sílẹ lọjọ òmìnira àádọ́rin ọdún ilẹ China
Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 3

Loni, ọjọ kinni, oṣu kẹwaa, ọdun 2019 naa ni orilẹ-ede China n sami ayajọ ominira aadọrin ọdun lẹyin ominira.

Orilẹ-ede Naijiria naa n sami ayẹyẹ ominira ọdun mọkandinlọgọta.

Ojo kinni, oṣu kẹwaa, ọdun 1949 ni Mao-Zedong ti ọpọ mọ si Chairman Mao kede ominira orilẹ-ede China tuntun.

Ifẹhonuhan ti suyọ loni ni ilẹ China to jẹ ayajọ ọjọ ominira ilẹ naa ni eyi ti pupọ ninu awọn ọmọ ilẹ naa ti tu jade lati féhonuhan ti o si jasi wahala.

china

Oríṣun àwòrán, Getty Images

Àkọlé àwòrán, China - Rògbòdìyàn bẹ sílẹ lọjọ òmìnira àádọ́rin ọdún ilẹ China

Iroyin fi ye wa pe, ọta ibọn ba ọkan lara awọn akọroyin to wa nibi ifẹhonu han naa.

Akọroyin naa ni o ṣeṣe nibi egbe oju rẹ ti awọn oludoola ẹmi si yara si i ki wọn to gbee lọ si ile iwosan.

Ṣaaju ni obinrin akọroyin naa ti sọ wi pe ọlọpaa kan ti kọkọ kọ oju ibọn si oun ni agọ wọn.

O ni ibọn yii lo kọ si oun ni ọna abajade si popona ila Oorun Ọmọbabinrin ilẹ naa.

Skip X post, 1
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 1

Awọn ọlọpaa ati ologun ni wọn kun oju popo ti wọn si n ṣe afihan ohun ija tuntun ti ijọba ilẹ naa ṣẹṣẹ ra.

Àkọlé fídíò, Nigeria Independence Day: Sé ẹ mọ̀ pé ọdún 1956 ló yẹ́ ká ti dòmìnira ṣùgbọ́n....

O ti di ọsẹ kẹtala bayii ti nkan ko tii fararọ ni orilẹ-ede China bayii. Boolọ o yago ni ọrọ di nigba ti ọta ibọn ati tajutaju n dun lakọ labo.

Olufẹhonu ilẹ China
Àkọlé àwòrán, Awọn olufẹhonu han

Bayii, gbogbo oju popo lo ti pa lọlọ ti ko si si igboke gbodo ọkọ bii igba ti ilẹ ṣẹṣẹ mọ.

Awọn oluworan ni wọn n wo ọgọọrọ awọn ọlọpaa ninu aṣọ dudu ati alawọ ewe ti wọn wọ.

Pẹlu bi gbogbo oju ọjọ ṣe ri ni ilẹ naa, ọpọ awọn olutaja ọti ni wọn ṣi ṣọọbu wọn kalẹ ti wọn n reti onibara.

Ileeṣẹ ọlọpaa China ni ifẹhonuhan ti n bi ige ati adubi ni eyi ti awọn agbofinro fi ni lati gbe igbesẹ to yẹ lasiko yii:

Skip X post, 2
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post, 2

Ni Beijing to jẹ olu ilu China ni wọn ti ṣeto ayẹyẹ ayajọ ominira China fun eto bi nkan bii wakati kan pere nibi ti awọn agbofinro ti duro wamuwamu ti wọn n ṣọ awọn eniyan.

Opo nkan ni awọn agbofinro fi di opopona ni Beijing ṣaaju ayẹyẹ ominira naa.

Sibẹ ọpọ arugbo ati ọmọde lo fi ayọ han si ayajọ ominira China pe aadọrin ọdun kuro ni keremi ninu ominira.

Nigba ti ọpọ ọdọ ko fi ayọ ominira yii han to pe o yẹ ki nkan ti ṣẹnu re ju bayii lọ ni China lẹyin aadọrin ọdun ominira.

Ọpọ awọn ti n fi ẹhonu han yii lojẹ ọdọ, ọmọ ile iwe ti o si ni atilẹyin awọn eekan ilu ninu.

Wọn ni awọn ọdọ n sọrọ nipa aini ọjọ ọla to peye ti alaṣẹ ilẹ China si n tẹ ominira ilẹ Hong Kong loju.

Eyi ni koko ohun to fa ifẹhonu naa han ti o si ti iṣu ata yanyan.