World Habitat Day: 'Ìjọba, ẹ ṣèrànwọ́ fáwọn tí kò rílé gbé ní Nàìjíríà'

Ibugbe lori omi

Oríṣun àwòrán, Twitter/Amnesty Int. Nigeria

Ìye àkókó tí a fi kà á: Ìṣẹ́jú 2

Ọjọ keje, oṣu kẹwaa, ọdọọdun ni ajọ iṣọkan agbaye, UNO ya sọtọ fun ayajọ ọjọ ibugbe ati lati ranti awọn ti wọn o rile gbe.

Ajọ UNO tun ya ọjọ naa sọtọ lati fihan wi pe ẹtọ awọn eeyan ti wọn ko ri ile ni lati lati ni igbegbe ti wọn naa.

Ọgbẹni Adamu Makoda, ẹni ọdun mẹrindinlaadọta to n gbe ilu Kano lorilẹ-ede Naijiria jẹ ọkan lara ogunlọgọ awọn eeya ti ko rile gbe ni Naijria.

Makoda sọ fun BBC pe airilegbe jẹ iṣoro to buru julọ ti ẹda le maa doju kọ laye.

''Ibi ti mo ti n sun niyi fun ibi ọdun marun un nitori mi o rowo ile san lẹyin ti okowo mi dẹnu kọlẹ, o ku diẹ kaato. Mi o gbadura ki ọta mi gan an koju iṣoro airilegbe.''

Adamu Makoda

Ọgbẹni Makoda rọ ijọba lati ṣeranwọ fawọn ti ko rile gbe ki wọn le maa gba ile olowo pọọku.

Adamu Makoda

''O ti pẹ ti mo ti n gbiyanju lati gba ile ki n le maa gbe pẹlu pọ pẹlu ẹbi mi, ṣugbọn ko si agbara.''

Makoda n kọminu lori ewu to wa ninu airilegbe rẹ nitori bi eto aabo ti mẹhẹ kaakiri orilẹ-ede Naijiria bayii.

Ẹwẹ, ajọ ajafẹtọ ọmọniyan, Amnesty Int. Nigeria ti rọ ijọba apapọ atawọn ti ipinlẹ lati dẹkun fifi ipa le awọn eeyan kuro nibi kan tabi ominiran.

Skip X post
Allow X content?

This article contains content provided by X. We ask for your permission before anything is loaded, as they may be using cookies and other technologies. You may want to read X cookie policy and privacy policy before accepting. To view this content choose 'accept and continue'.

Warning: Third party content may contain adverts

End of X post

Ajọ Amnesty ṣafihan ninu aworan kan ti wọn fi lede loju opo Twitter wọn awujọ kan ti ko si ile igbọnsẹ, omi mimu to dara ati ọna gidi.

Akọsilẹ fihan pe ẹgbẹlẹgbẹ ọmọ Naijiria ni kori ile gbe, awọn eeyan yii si ni ireti pe awọn naa yoo rile gbe lọjọ kan.

Àkọlé fídíò, Africa Eye: Olùkọ́ méjì ní fásitì Eko àti Ghana lùgbàdì ọ̀fíntótó BBC lórí ìwà ìbàjẹ́