BBNaija: Kayọde Ogundamisi ní akọ́nilọ́gbọ́n, amúlùúdùn ni BBNaija, kìí ṣe òṣèlú

Awọn oludije to kopa lori eto BBNaija

Oríṣun àwòrán, @BBNaija

Eto BBNaija ti wa, to si ti lọ amọ ariyanjiyan nipa pataki eto naa sawọn ọmọ Naijiria ko tii buse.

Ọpọ ọmọ Naijiria lo n beere pe ki ni awọn ọdọ ri ti wọn se n suru bo eto naa nigba to jẹ pe awọn ọrọ miran to se koko wa nilẹ Naijiria, eyi to nilo ki wọn kọbi ara si wọn.

Yatọ si eyi, iye ibo ti awọn ọdọ di lori BBNaija ati iye owo ti irufẹ awọn ibo yii pa wọle si apo awọn eeyan to se agbatẹru eto naa gan, tun n kọ awọn ọmọ́ Naijiria kan lominu.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Gẹgẹ baa se gbọ, miliọnu lọna ogoje ni apapọ ibo tawọn ọdọ di fun oludije kan abi omiran lori eto ọhun, bi o tilẹ jẹ pe awọn miran di ibo ju igba meji tabi mẹta lọ.

Olukayode Ogundamisi

Oríṣun àwòrán, @BBNaija

Àkọlé àwòrán, Olukayode Ogundamisi ti ní kí àwọn ọmọ Naijiria yé bu ẹnu àtẹ́ lu Big Brother Naija, nítorí óhún mú inú àwọn ènìyàn dùn.

Taa ba si gbe eyi fẹgbẹkẹgbẹ pẹlu apapọ ibo taa di lasiko ibo aarẹ ni Naijiria, ọna jin si ara wọn nitori ibo miliọnu mejidinlọgbọn o le diẹ ni ajọ eleto idibo kede pe ọmọ Naijiria di lasiko ibo aarẹ to kọja.

Idi si ree ti awọn ọmọ Naijiria se n beere pe, ki ni pataki eto BBNaija fawọn ọdọ, eyi to lowura ju eto iyansipo olori isejọba Naijiria lọ?

Nigba to n dahun ibeere yii, oludamọran lori ọrọ ilu ati ilẹ okeere, Olukayode Ogundamisi ni nkan arikọgbọn pọ lorisirisi ninu ere Big Brother Naija.

Ogundamisi, lasiko to n ba BBC Yoruba sọrọ, salaye siwaju pe, awọn ọmọ Naijiria n mu inu ara wọn dun lori eto naa, ati wi pe, ohun idanilaraya lo jẹ fun wọn.

Mercy n gba ẹ́bun to jẹ

Oríṣun àwòrán, @BBNaija

O fikun wi pe ọrọ ki ilu dara tabi ko gbooro ko nii se pẹlu ere idaraya, ati wi pe, a ko gbọdọ dina awon eniyan lati je ki won wo nkan to ma a mu inu wọn dun.

Oludamọran lori ọrọ ilu ati ilẹ okeere naa ni, ko si ohun to ti ni loju ninu eto adanilaraya, ati wi pe awọn eniyan fẹran idaraya ju ogun tabi ija lọ.

Ogundamisi ni ko si nkan to buru ninu rẹ nitori ko si wi pe awọn eniyan n dibo pẹlu ipaya pe, laasigbo tabi wahala le bẹ silẹ lawujọ.

Amọ, o parọwa si awọn ọdọ lati mu isẹ wọn ni ọkunkundun, ti wọn si jẹ ki ọro ilu naa ka wọn lara lati le mu igbelarugẹ ba orilẹede Naijiria.