APC Crisis: Àwọn jàndùkú kọlu Ọba Eko àti Gomina ìpínlẹ̀ Edo lọ́nà ilé Oshiomole

Oríṣun àwòrán, Facebook/Godwin Obaseki
Awọn janduku kan niroyin sọ pe wọn kọlu Ọba ilu Eko, Ọba Rilwan Akiolu ati Gomina ipinlẹ Edo, Godwin Obaseki loju ọn wọn si ile alaga gbogbo ẹgbẹ oṣelu APC, Adams Oshiomole ni Iyamoh nipinlẹ Edo lọjọ Satide.
Ohun ti a gbọ ni pe awọn ọdọ janduku ri ọkunrin kan, Andrew Momodou ti wọn fẹsun kan o ṣagbatẹru ikọlu to waye nile Oshiomole niluu Benin nibi to ti n kọwọ rin pẹlu Oba Eko, Gomina Obaseki ati Baba isalẹ Fasiti ipinlẹ Edo, Ọjọgbọn T.O.K. Audu.
Gomina Obaseki atawọn alejo rẹ lọ sibi ayẹyẹ ikẹkọgboye ni fasiti ọhun niluu Iyahmo, ni ijọba iible Etsako ki wọn to mori ile ibugbe Oshiomole lagbegbe naa.
- Mátikú; Oba ìlú Eko tó forí oyè sílẹ̀ lọ́dún 1931 kí àlàáfíà lè jọba
- Yinka Quadri: Mo dúpẹ́ pé Ogogo jẹ́ ọ̀rẹ́ mi!
- Ẹni kan ti gbẹ́mìí mì; àwọn mẹ́rin ń gba ìtọ́jú nílé ìwòsàn-LASEMA
- Kò sí aàyè fún ìbò rírà àti títà ni Kogi àti Bayelsa- IGP
- Èèdì rèé o! Olùkọ́ fẹgba lu akẹ́kọ́ọ̀bìnrin ọmọ ọdún mẹ́rìnlá pa ní yàrá ìkàwé
- Àwọn ọkùnrin tó wà nínú ayé wa gbúdọ̀ bọ̀wọ̀ fún wa - Olùdásílẹ̀ FIN
Ẹnikan ti iṣẹlẹ naa ṣoju rẹ ṣalaye pe Oshiomole lo pe Oba Eko ati Gomina Ipinlẹ Edo lati wa ṣ awẹjẹ-wẹmu nile rẹ lẹyin ayẹyẹ ikẹkọgboye ni fasiti ipinlẹ naa.
Awọn ẹṣhọ to tẹ le gomina ipinlẹ Edo lo pẹtu saawọ naa, bibẹẹkọ, afaimọ ki iṣẹlẹ ọhun ma mu ẹmi lọ.
Ẹlomiiran tọrọ naa ṣoju ni igbakeji gomina ipinlẹ Edo, Philip Shaibu to ko awọn ọlọkada bii lọ si ibi ayẹyẹ ikẹkọọgboye naa lo fa iṣẹlẹ ọhun.
Ọpọ ọkọ to te le Gomina Obaseki ati Oba Eko lawọn janduku fọ gilaasi wọn.








