Corruption: Ọ̀gá àgbà àṣọbodè ní kíkọ rìbá ṣàfihàn aṣọ́bodè tó ti di àtúnbí

Ilé iṣẹ́ aṣọ̀bode ti ṣe àgbéga fún ọ̀gá àgbà ilé iṣẹ rẹ̀ ní Apapa, Bashir Abubakar sí ipò igbákejì ọgá agba ileeṣẹ náà.
Col. Hameed Ibrahim Ali gbé Muhammed Abba-Kura ga si ipo oludari àgbà ní agbègbè Apapa.
Abubakar kọ ààdọ́jọ mílíọ̀nù náírà, owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ ti olóògùn fàyàwọ́ kan fi lọ̀ọ́, láti gbé òògùn ogoji ọkọ ajagbé tó kún fún Tramadol wọle.
Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:
- Ọmọ Nàíjíríà tó jẹ́ Ìmáàmù mọ́ṣálásí tí wọn kọlù ní New Zealand ṣàlàyé ìṣẹ̀lẹ̀
- Yorùbá, ọmọ ọdún mẹ́jọ tà ọmọ òyìnbò yọ nínú ayò Chess l‘Amẹrika
- Pius Adesanmi ní kò bá rọ́pò Wole Soyinka tí kò bá kú - ọmọ Naijiríà
- Àwọn tó gboriyin àti àwọn tó gbàbuku lórí ìṣẹlẹ New Zealand
- Àìsàn tó ń ṣe ọ ní ohun ṣe pẹlú oorun rẹ - Onímọ
Ìròyìn fi ye ní pé, ọgá aṣọ́bodè àti àwọn ìsọ̀gbè rẹ̀ kọ owó àbẹ̀tẹ́lẹ̀ náà, wọn si fi ìdí àwọn àjàgbé tó kúń fún àwọn oogun náà gúnlẹ̀, èyí tó lé ní bílíọ̀nù méje naira.
Lásìkò tó ń ba àwọn akọròyin sọ̀rọ̀ lọ̀rí ọ̀rọ̀ to ṣẹ̀lẹ̀ nínú oṣù kọkànlá òsu 2018, ọgá àgbà pátápáta fawọn aṣọbodè sọ pé " kíkọ ààdọ́jọ mílíọ̀nù náírà owó àbẹ̀tẹ̀lẹ̀, sàfihan àwọran òṣìṣẹ́ aṣọ́bode tó ti gbà àtúnṣe, ti wọn sì ń fi ọ̀rọ̀ àrá ìlú sáájú ju imọ̀ tara ẹni nikan lọ.

Oríṣun àwòrán, Getty Images
O ní onífàyàwọ́ ọ̀hún tún jẹ́ẹ̀jẹ́ pé òun yóò sàn rìbá tó tún pọ̀ jùbẹ́lọ ti tí àkọ́kọ́ yìí ba ṣe dáradára.









