Tani: Boko Haram ló lé àwọn òbí rẹ̀ lọ sí Amẹrika

Tanitoluwa Adewunmi

Ọmọ ọdun mẹjọ ni Tanitoluwa Adewunmi wa, to fi kopa pẹ́lu awọn akẹẹgbẹ rẹ ti wọn jẹ ọjẹ wẹwẹ nilẹ́ Amẹrika, fun idije ẹni to pegede julọ ninu idije ayo Chess.

Sugbọn Ọlọrun se Tanitoluwa, ti gbogbo eeyan mọ si Tani logo, nigba to ta awọn akẹ ẹgbẹ rẹ to jẹ alawọ funfun yọ, to si di ẹni to gbe igba oroke ninu idije New York state Chess Championship

Gẹgẹ bi iwadi ikọ Newsday to wa labẹ ileesẹ iroyin BBC ti wi, Itajẹsilẹ ikọ adunkoko mọni Boko Haram lo le awọn obi Tani, eyiun Kayọde ati Oluwatoyin kuro ni Naijiria, ti wọn si lọ sorilẹede Amẹrika lati lọ se atipo.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Nkan ko san mọna fun lọkọlaya naa nigba ti wọn de Amẹrika, inu ahere ti kii se ile rara, si ni wọn n gbe pẹlu ẹgbọn ọmọ naa.

Lasiko to n ba BBC sọrọ lori aseyọri rẹ yii, Tani salaye pe inu mọto oun ni oun ti bẹrẹ si ta ayo Chess, ti oun si gbaradi fun idije naa, nipa lilo awọn ohun eelo ere Chess igbalode to wa fawọn ọmọde.

Tani fikun pe, lẹyin ti oun ba de lati ile iwe, ti oun si jẹun tan, to ba di aago meje, ni oun yoo ta ayo Chess fun wakati mẹta.

Tanitoluwa Adewunmi

Tani fikun pe "Ayo Chess maa n jẹ ki eeyan lee ronu jinlẹ, tẹ ba ta bo se yẹ kẹ ta, idi niyi ti mo se fẹran rẹ.

Mo fẹ jẹ ọmọde to dantọ julọ ninu Chess lagbaye, ki n si lewaju ninu akọsilẹ fun awọn alaseyọri to lewaju lagbaye"

Nigba toun naa n salaye bi Tanitoluwa se bẹrẹ ayo Chess, mama rẹ, Oluwatoyin ni ọdun 2018 lo bẹrẹ ayo naa, eyiun bii ọdun kan sẹyin.

"Ileewe to n lọ ni wọn ti ya ọjọ kan sọtọ fun ẹgbẹ awọn to n ta ayo Chess ni Ọjọbọ lọsọọsẹ. Boya bo se ta ayo naa lo wu wọn lori. Olukọ rẹ lo fi iwe kan ransẹ si mi pe Tanitoluwa nifẹ lati maa ta ayo Chess, yoo si dara ti mo ba lee ba olukọni wọn sọrọ."

Tanitoluwa Adewunmi, awọn obi ati ẹgbọn rẹ

Mama Tani salaye siwaju pe idi ree ti oun se fi email sọwọ si olukọni naa pe, se yoo gba Tani lati darapọ mọ ẹgbẹ alayo Chess wọn.

"Olukọni naa ni ko si wahala, sugbọn ko si owo kankan lọwọ mi, mo si yara tete jẹwọ ipo ti mo wa fun wọn pe, inu ahoro kan ni mo n gbe, ko si si owo kankan lọwọ mi."

Lẹyin to fi mail ransẹ si olukọni naa tan, onitọun ni ko si wahala, ti oun ko ba ni owo lọwọ, o si gba Tani sagbo wọn lọfẹ.

Tanitoluwa Adewunmi

Oluwatoyin, pẹlu iwuri ni "ọmọ daada ni Tani, o si ni ọpọlọ pipe, sugbọn boya nitori emi ko ta ayo chess ri, mo kan ro pe ere ayo ti wọn n ta nile iwe ni, n ko lero pe o lee ta ọmọ mi yọ si gbangba bi eyi."

Ogo Yoruba ni tanitoluwa Akinwunmi jẹ, ọmọ to si yẹ ka maa foju sọna fun pe yoo gbe ogo ilẹ Yoruba ga loke okun ni.