Lagos-Ibadan Express Road: Ìjọba àpapọ̀ ní òun yóò ṣí ọ̀nà tó tì padà ní Dec 15 fọ́dún Kérésì

Awọn ọkọ epo to di opopona marosẹ Ibadan si Eko pa

Oríṣun àwòrán, AFP

Ijọba apapọ ti kede pe gbogbo awọn ọna ti wọn ti pa lopopona marosẹ Ibadan silu Eko ni yoo di ṣiṣi pada lati ọjọ Kẹẹdogun oṣu kejila ọdun 2019.

Oludari ẹka to wa fun amojuto awọn opopona to jẹ tijọba apapọ lẹkun iwọ oorun guusu orilẹede yii, Funsọ Adebiyi lo fọwọ idaniloju yii sọya, lasiko to n ba awọn awakọ ajagbe ejo takurọsọ ni agbegbe Ogere nipinlẹ Ogun.

Àwọn iròyin tì ẹ leè ní ìfẹ̀ síí:

Adebiyi ṣalaye pe ijọba yoo ṣi awọn oju ọna ọhun pada lati ri i daju pe sunkẹrẹ fakẹrẹ ọkọ dinku, ti opopona marosẹ Ibadan si Eko yoo si ja gaara lasiko ọdun keresi pẹlu afikun pe, isẹ yoo bẹrẹ pada lẹyin ọdun keresi.

Abala marosẹ Ibadan si Eko ti isẹ atunse n waye nibẹ

Oríṣun àwòrán, @Biodunpen

O fi kun un pe "Kilomita marundinlaadọrin ti pari lopopona marosẹ ọhun, ti ogun kilomita to ti pari si wa ni abala kinni lati ẹnu bode atijọ lọ si ikorita ọna Ṣagamu eyi ti ileesẹ Julius Berger n ṣe, nigba ti kilomita marundinlaadọta naa ti pari ni abala keji eyi ti ileesẹ RCC n ṣe."

Ko tan sibẹ, Adebiyi wa paṣẹ fun awọn ọlọkọ ajagbe naa lati gbe ọkọ wọn kuro ni agbegbe Ogere ti iṣẹ ọna lila ko ni pẹ de ibẹ tabi ki wọn rin sẹyin bii aadọta mita kuro ni ibi ti iṣẹ oju ọna ọhun yoo gba kọja.

Abala marosẹ Ibadan si Eko ti isẹ atunse n waye nibẹ

Oríṣun àwòrán, @Biodunpen

Oludari akoso oju ọna tun fi kun un pe lootọ ni ijọba lee lo agbara lati le wọn kuro ni agbegbe yii amọ oun wa parọwa si wọn naa gẹgẹ bii ọmọ iya, nitori ijọba gba pe eyi san ju lilo iwa ipa lọ.

O wa ṣisọ loju rẹ pe, ileesẹ RCC ti so iṣẹ to n ṣe loju ọna marosẹ Ibadan si ilu Eko ni agbegbe Ogere rọ na, nitori bi awọn ọlọkọ ajagbe ejo naa ṣe duro soju ọna laibikita eyi to n di iṣẹ lila oju ọna naa lọwọ.